Padà

Èdè Yorùbá

يوربا

Ẹkọ pataki

1 vidẹẹo
PDF

Wudu

3 vidẹẹo
Description of Wudu
0:00 / 0:00
How to Perform Wudu
0:00 / 0:00
Wudu Affairs
0:00 / 0:00

Adura

3 vidẹẹo
Description of Prayer
0:00 / 0:00
Salah with Duaa
0:00 / 0:00
How to Perform Prayer
0:00 / 0:00

Ibeere pataki

272 ibeebi
“Abala igbagbọ”42

Ìbéèrè àkọ́kọ́: Ta ni Ọlọhun Rẹ? “

“Idahun- Allahu ni Oluwa mi ẹni ti o ṣe pe Oun ni O n tọju mi ti O si n tọju gbogbo agbaye pẹlu idẹra Rẹ. “
“Ẹri ni:
Ọ̀rọ̀ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-: “ Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá, 2 [Surah Al-Fâtihah: 2]

"Ibeere ẹlẹẹkeji: ki ni ẹsin rẹ? "

"Idahun- Ẹsin mi ni Isilaamu, oun ni: Jijupa-jusẹ fun Ọlọhun pẹlu igbagbọ ninu Ẹ ni Oun nikan ṣoṣo, ati itẹriba fun Un pẹlu itẹle, ati mimọ kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹlẹbọ. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. [Surah Âl-`Imrân: 19]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹta: Ta ni Anọbi rẹ? "

"Idahun- Anọbi Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu ...} "[Surah Al-Fath: 29]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹrin: Darukọ Kalmatut Taohīd (gbolohun igba Ọlọhun gbọ ni ọkan ṣoṣo), ati pe ki ni itumọ ẹ? "

"Idahun- Kalmatut Taohīd ni "Laa ilaaha illallahu", itumọ ẹ ni pe: Ko si ẹni tí ijọsin ododo tọ si afi Allahu. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. "[Suuratu Muhammad: 19]"

"Ibeere ẹlẹẹkarun-un: Ibo ni Ọlọhun - ti O lágbára ti O gbọnngbọn - wa? "

"Idahun- Ọlọhun n bẹ ni sanmọ lori itẹ-ọla, lori gbogbo ẹda, Ọba -ti ọla Rẹ ga- sọ pe: " "{Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá 5} "[Surah Tâ-hâ: 5]" O sọ pe: "{Òun sì ni Olùborí t’Ó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ 18} "[Surah Al-An`âm: 18]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹfa: Ki ni itumọ jijẹrii pe dajudaju Muhammad ni Ojiṣẹ Ọlọhun? "

"Idahun- Itumọ ẹ ni pe: Ọlọhun ni O ran an si gbogbo aye ni olufunni ni iro ìdùnnú ati olukilọ "
"O si jẹ dandan: "
"Titẹle e nibi nnkan to ba pa laṣẹ. "
"Gbigba a lododo nibi nnkan ti o ba sọ. "
"Ki a ma ṣẹ ẹ. "
"Ki a ma jọsin fun Ọlọhun afi pẹlu nnkan ti O ṣe lofin, oun ni itẹle oju-ọna ojiṣẹ Ọlọhun ati gbigbe adadaalẹ ju silẹ. "
"Ọba -ti ọla Rẹ ga- sọ pe-: {Ẹnikẹ́ni t’ó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu...} [Suuratun Nisâ': 80], O tun sọ- mimọ ni fun Un- pe: {Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú 3 Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i 4} "[Suuratun Najm: 3, 4] "Ọba - ti O lágbára ti O gbọnngbọn - sọ pe: " "{Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fun yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà) 21} [Surah Al-Ahzâb: 21]"

"Ibeere ẹlẹẹkeje: Nitori ki ni Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ṣe da wa?"

"Idahun- O da wa fun ijọsin Rẹ ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun kankan fun Un. "
"Ko kii ṣe tori iranu ati ere. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi 56} "[Surah Adh-Dhâriyât: 56]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹjọ: Kí ni o n jẹ ijọsin? "

"Idahun- Oun ni orukọ kan to ko gbogbo nnkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ rẹ ati nnkan ti O yọnu si ninu awọn ọrọ ati iṣẹ ti o pamọ ati èyí tí o han sinu."
"Eyi to han:
Gẹgẹ bii iranti Ọlọhun pẹlu ahọn ninu iṣe afọmọ, ati idupẹ, ati igbe Ọlọhun tobi, ati kiki irun ati ṣiṣe Hajj. "
"Eyi to pamọ:
Gẹgẹ bii igbarale Ọlọhun ati ibẹru ati agbiyele. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹsan-an: Ki ni nnkan to tobi julọ ti o jẹ dandan fun wa? "

Idahun- "Nnkan to tobi julọ ti o jẹ dandan fun wa ni: Nini igbagbọ ninu Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ni Òun nikan ṣoṣo. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹwaa: Ki ni awọn iran Taohīd (nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo)? "

"Idahun-1- Taohīdur Rubūbiyyah: Oun ni nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun ni Adẹdaa, Olupese, Olukapa, Oluṣeto, ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun kankan fun Un. "
"2- Taohīdul 'Ulūhiyyah: Oun ni imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin, ti a o si nii jọsin fun ẹnikankan afi Allahu -ti ọla Rẹ ga- "
"3- Taohīdul ’Asmā’i was Sifāt: Oun ni nini igbagbọ ninu awọn orukọ ati awọn iroyin ti Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ti o wa ninu iwe Ọlọhun ati ọrọ ojiṣẹ Ọlọhun, laisi isafiwe tabi afijọ tabi sisọ pe ko ri bẹẹ. "
"Ẹri awọn iran nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo mẹtẹẹta ni:
ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga - to sọ pe:" {Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀? 65} " [Surah Maryam: 65]"

"Ibeere ẹlẹẹkọọkanla: Ki ni ẹṣẹ ti o tobi julọ? "

"Idahun- mimu orogun pẹlu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga”
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá 48}" "[Surah An-Nisâ': 48]"

"Ibeere ẹlẹẹkejila: Darukọ ẹbọ ati awọn iran rẹ?"

"Idahun- Ash-Shirku: Oun ni gbigbe eyikeyi iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹlomiran yatọ si Ọlọhun ti ọla Rẹ ga”
"Awọn iran ẹ: "
"Ẹbọ nla; gẹgẹ bii: Pipe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, tabi fifi ori balẹ fun ẹni ti o yatọ si I -mimọ fun Un-, abi didu ẹran fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun - ti O lágbára ti O si tun gbọnngbọn-. "
"Ẹbọ kekere; gẹgẹ bii:
Bibura pẹlu nǹkan ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, tabi At-Tamā’im (asokọrun), oun naa ni nnkan ti wọn maa n so kọ lati fi fa anfaani wa tabi ti aburu danu, ati eyi to kere ninu ṣekarimi, gẹgẹ bii ki o maa ki irun rẹ dáadáa latari pe o n ri awọn ti wọn n wo o. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Ǹjẹ́ ẹnikankan yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ni imọ ikọkọ? "

"Idahun- ẹnikankan o ni imọ ikọkọ afi Ọlọhun nikan ṣoṣo. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Sọ pé: “Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde 65} " "[Suuratun Naml: 65]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinla: Onka awọn origun igbagbọ? "

"Idahun- 1- Nini igbagbọ ninu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga”
"2- Ati awọn Malaika Rẹ."
"3- Ati awọn iwe Rẹ. "
"4- Ati awọn Ojiṣẹ Rẹ."
"5- Ati ọjọ ikẹyin. "
"Ati kadara eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru."
"Ẹri ni:
Hadisi Jibril ti o gbajumọ lọdọ Muslim, Jibril sọ fun Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: " "«Fun mi ni iro nipa igbagbọ, o sọ pe: Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o ni igbagbọ ninu kadara eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru». "

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogun: Ṣe alaye awọn origun igbagbọ? "

"Idahun- Nini igbagbọ ninu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: "
"Ki o ni igbagbọ pe dajudaju Allahu ni O da ọ ti O si n pese fun ọ, Oun nikan ṣoṣo ni Olukapa ati Oluṣeto gbogbo ẹda. "
"Oun ni Ẹni ti a n jọsin fun, ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si yatọ si I."
"Dajudaju Oun ni Ọba ti O tobi, Ọba nla, Ọba ti O pe julọ ti O ṣe pe gbogbo ọpẹ patapata n jẹ tiRẹ, awọn orukọ to rẹwa ati awọn iroyin to ga n jẹ tiRẹ, ko si orogun fun Un, nnkankan o si jọ Ọ (mimọ ni fun Un). "
" Nini igbagbọ ninu awọn Malaika:
"
"Awọn ni ẹda ti Ọlọhun da wọn latara imọle, ati fun ijọsin Rẹ ati fun itẹle to pe fun aṣẹ Rẹ"
"Ninu wọn ni Jibrīl -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- wa, ẹni ti o ṣe pe o maa n sọkalẹ pẹlu imisi fun awọn Anọbi."
"Nini igbagbọ ninu awọn iwe:
"
Awọn ni awọn iwe ti Ọlọhun sọ wọn kalẹ fun awọn Ojiṣẹ Rẹ. "
"Gẹgẹ bii Kuraani:
Ti a sọkalẹ fun Muhammad -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-"
"Injīl:
Ti a sọkalẹ fun Isa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Taorah:
Ti a sọkalẹ fun Musa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Zabūr:
Ti a sọkalẹ fun Dāud -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Awọn takada Ibrāhīm ati Mūsa:
Ti a sọkalẹ fun Ibrohim ati Musa."
Nini igbagbọ si awọn ojiṣẹ [Ọlọhun]
"Awọn ni ẹni ti Ọlọhun ran wọn si awọn ẹru Rẹ lati kọ wọn (ni ẹsin), ati lati fun wọn ni iro idunnu pẹlu daadaa ati alujanna, ati lati ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi aburu ati ina. "
"Awọn ti wọn lọla julọ ninu wọn ni:
Awọn onipinnu, awọn si ni:
" Nūh -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
" Ibrāhīm -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Mūsa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Ēsa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Muhammad -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-."
Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin.
"Oun ni nnkan to wa lẹyin iku ninu sàréè, ati ni ọjọ ajinde, ati ọjọ igbende ati iṣiro, ni ibi ti awọn ero alujanna o ti maa wa ni awọn ibugbe wọn ti awọn ero ina naa o si maa wa ninu awọn ibugbe wọn."
"Nini igbagbọ ninu kadara eyi to daa ninu ẹ ati eyi to buru:
"
"Al-Qadar (Kadara): Oun ni nini adisọkan pe dajudaju Ọlọhun ni imọ nipa gbogbo nnkan ti o n ṣẹlẹ ninu aye, ati pe O ti kọ yẹn sinu Laohul Mahfūdh (ọpọn ti A n ṣọ ti akọsilẹ gbogbo nkan wa ninu rẹ), O si tun fẹ bibẹ rẹ ati dida a. "
"Ọba ti ọla Rẹ ga- sọ pe {Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá 49}[Surah Al-Qamar: 49]."
" Ipele mẹrin ni o ni:
"
"Alakọkọ: Imọ Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, ninu iyẹn ni imọ Rẹ to ti ṣaaju gbogbo nnkan, ṣíwájú ṣiṣẹlẹ awọn nnkan ati lẹyin ṣiṣẹlẹ rẹ. "
"Ẹri ẹ ni:
Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun t’ó wà nínú àpòlùkẹ́. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán. 34 [Suuratu Luqman: 34].
"Ẹlẹẹkeji:
Dajudaju Ọlọhun ti kọ yẹn sinu Laohul Mahfūdh (ọpọn ti A n ṣọ ti akọsilẹ gbogbo nkan wa ninu rẹ), ati pe gbogbo nnkan to sẹlẹ ati èyí tí yoo ṣẹlẹ jẹ nnkan ti wọn ti kọ si ọdọ Rẹ sinu iwe "
"Ẹri ẹ ni:
Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú. 59 [Suuratul-An’am: 59].
"Ẹlẹẹkẹta:
Oun ni pe gbogbo nnkan n ṣẹlẹ pẹlu ifẹ Ọlọhun, nnkankan o nii ṣẹlẹ lati ọdọ Rẹ tabi lati ọdọ ẹda Rẹ afi pẹlu ifẹ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga- "
"Ẹri ẹ ni:
Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé 28 Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá 29} "[Suuratut Takwîr: 28]"
"Ẹlẹẹkẹrin: Nini igbagbọ pe gbogbo nnkan ti o n bẹ ẹda ni wọn ti Ọlọhun da wọn, ti O si da awọn paapaa wọn ati awọn iroyin wọn ati lilọ bibọ wọn, ati gbogbo nnkan ti o n bẹ ninu wọn. "
"Ẹri ẹ ni:
Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ 96} [Surah As-Sâffât: 96]

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlogun: Ki ni alaye (itumọ) Al-Qur'ān? "

"Idahun- Ọrọ Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ni, kii ṣe nnkan ti a da. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu...} [Suuratu At-Tawbah: 6].

Ibeere 17: Ki ni n jẹ Sunnah?

Idahun- Oun ni gbogbo ọrọ tabi iṣe tabi ifirinlẹ tabi iroyin ti dida tabi ti iwa ti n bẹ fun Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).

Ibeere 18: Ki ni a n pe ni adadaalẹ? Ati pe ṣe a maa gba a?

Idahun- Gbogbo nkan ti awọn eeyan ba daalẹ sinu ẹsin, ti ko si si nigba aye Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati awọn saabe rẹ.
A o nii gba a, ati pe a maa da a pada ni.
Fun ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Gbogbo adadaalẹ pata anu ni Abu Daud ni o gba a wa.
Apejuwe rẹ:
Alekun nibi ijọsin, gẹ́gẹ́ bíi ṣiṣe alekun fifọ ẹlẹẹkẹrin nibi aluwala, ati ṣiṣe ayẹyẹ ọjọ-ibi Anabi, ko wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati awọn saabe rẹ.

Ibeere 19: Sọ nkan ti n jẹ adisọkan Al-Walā’a ati Al-Barā’u?

Idahun- Al-Walā’u: Oun ni nini ifẹ awọn onigbagbọ ododo ati ṣiṣe iranwọ fun wọn.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan...}. [Suuratu At-Tawbah: 71].
Al-Barāhu: Oun ni ikorira awọn alaigbagbọ ati iba wọn ṣọta.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fun yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. [Suuratul-Mumtahina: 4].

Ibeere 20: Njẹ Ọlọhun o gba nkan to yatọ si Isilaamu ni ẹsin?

Idahun- Ọlọhun o nii gba nkan ti o yatọ si Isilaamu.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò 85}. [Suuratu Al-Imran 85]"

"Ibeere ẹlẹẹkọkanlelogun: Aigbagbọ a maa jẹ pẹlu ọrọ ati ìṣẹ ati adisọkan, mu àpẹrẹ wa fun iyẹn? "

"Idahun- Àpẹrẹ ọrọ: Bibu Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tabi Ojiṣẹ Rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-."
"Àpẹrẹ iṣẹ:
Yiyẹpẹrẹ Kuraani tabi fifi ori kanlẹ fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
"Àpẹrẹ adisọkan:
Didi adisọkan pe nnkankan n bẹ ti o lẹ́tọ̀ọ́ si ijọsin yatọ si Allahu -ti ọla Rẹ ga- tabi pe adẹda kan nbẹ pẹlu Allahu -ti ọla Rẹ ga-. "

"Ibeere ẹlẹẹkejilelogun: Ki ni ṣọbẹ-ṣelu ati awọn iran rẹ? "

"Idahun- "
"1- Sọbẹ-ṣelu nla: Oun ni fifi aigbagbọ pamọ ati ifi igbagbọ han. "
"Yio maa mu ni kuro ninu Isilaamu, o wa ninu aigbagbọ nla. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn 145} "[Suuratun Nisaa: 145]"
"2- Sọbẹ-ṣelu (Oju eji) kekere: "
"Gẹgẹ bii: Irọ ati iyapa adehun ati ijanba afọkantan. "
"Ko nii mu ni kuro ninu Isilaamu, o wa ninu awọn ẹṣẹ ati pe ẹni ti o n ṣe e maa lẹ́tọ̀ọ́ si iya. "
"Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " Àmì ti a fi n da munafiki mọ mẹta ni: Ti o ba sọrọ yóò parọ, ti o ba ṣe àdéhùn yóò yapa, ti wọn ba gbára le e yóò jamba "Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹtalelogun: Ta ni opin awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ? "

"Idahun- oun ni Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì...} " [Suuratul-Ahzaab: 40]. "- Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " «Emi ni opin awọn Anabi, ko si Anabi kankan lẹyin mi» " "Abu Daud ati Tirmidhi ati ẹni ti o yatọ si wọn ni wọ́n gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinlelogun: Ki ni iṣẹ-iyanu? "

"Idahun- iṣẹ-iyanu ni: Gbogbo nnkan ti Ọlọhun fun awọn Anabi Rẹ ninu awọn nǹkan eemọ lati da lori ododo wọn, gẹgẹ bii: "
"Lila oṣupa si meji fun Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "
"- Pinpin odo si meji fun Musa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ati titẹri Fir'aun ati awọn ọmọ ogun rẹ. "

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlọgbọn: Ta ni awọn sọhaba? Àti pe ṣe maa nífẹ̀ẹ́ wọn? "

"Idahun- Sàábé ni: Ẹni ti o ba pade Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o gba a gbọ ti o si ku sori Isilaamu. "
"- A maa nífẹ̀ẹ́ wọn, a si maa kọ iṣe wọn, awọn ni ẹni ti o dara julọ ti wọn si lọla julọ ninu awọn eeyan lẹyin awọn Anabi. "
"Awọn ti wọn lọla julọ ninu wọn ni awọn arole mẹrẹẹrin:
"
"Abu Bakr -ki Ọlọhun yọnu si i-."
"Umar -ki Ọlọhun yọnu si i-.
"Uthman -ki Ọlọhun yọnu si i-.
"Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i-. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlọgbọn: Àwọn wo ni awọn iya awọn onigbagbọ? "

"Idahun- awọn ni awọn iyawo Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn} [Suuratul-Ahzaab: 6].

"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn: Ki ni iwọ awọn ara ile Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o jẹ dandan fun wa?"

"Idahun- A maa nífẹ̀ẹ́ wọn, a si maavmu wọn ni ọrẹ, a si maa korira ẹni ti o ba korira wọn, a o si nii kọja aala nipa wọn, awọn ni awọn iyawo rẹ ati awọn arọmọdọmọ rẹ, ati awọn ọmọ Hashim ati awọn ọmọ Mutollib ninu awọn onigbagbọ. "

"Ibeere ẹlẹẹkejidinlọgbọn: Ki ni ojuṣe wa si awọn adari alamọri awọn musulumi? "

"Idahun- Ojuṣe wa ni: Ṣíṣe apọnle wọn, ati gbigbọ ati titẹle wọn nibi nnkan to yatọ si yiyapa Ọlọhun, ki a si ma jáde le wọn lori, ki a si maa ṣe adura ati iṣiti fun wọn ni kọrọ."

"Ibeere ẹlẹẹkọkandinlọgbọn: Ki ni ile awọn onigbagbọ? "

"Idahun- alujanna (ọgba idẹra)" "{Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀...} [Suuratu Muhammad: 12].

Nibo ni ile awọn alaigbagbọ?

Ina ni, Ọlọhun ti O ga sọ pe: nítorí náà ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́. 24 [Suuratul-Baqarah: 24].

Ki ni wọn n pe ni ibẹru? Ki ni wọn n pe ni agbiyele? Ki si ni ẹri?

Ibẹru: Oun ni bibẹru Ọlọhun ati iya Rẹ.
Ṣíṣe agbiyele:
Oun ni ṣiṣe agbiyele ẹsan lọdọ Ọlọhun ati aforijin Rẹ ati ikẹ Rẹ.
Ẹri:
Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti O ga: Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn l’ó súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? – Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. 57 [Suuratul-Israa: 57]. Allah tun sọ pe: Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 49 Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro 50 [Suuratul-Hijr: 49, 50].

Ibeere ẹlẹẹkejilelọgbọn: Dárúkọ apa kan awọn orukọ ati awọn iroyin Ọlọhun ti O ga julọ?

Idahun- Ọlọhun, Ọba Olutọju, Onikẹẹ, Olugbọ, Oluriran, Onimimọ, Olupese, Alaaye, Ọba ti O tobi.... ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn orukọ ti o dara ati awọn iroyin ti o ga.

Ibeere ẹlẹẹkẹtalelọgbọn: Ṣe alaye awọn orukọ yii?

Idahun- ALLAAHU: Ìtumọ̀ rẹ ni pe Ọba ti a n sin ni ododo, Oun nikan ni O da wa ti ko si ni akẹgbẹ.
AR-ROBB: Ìtumọ̀ rẹ ni Oludẹdaa, Olukapa, Olupese, Oluṣeto ni Oun nikan ṣoṣo, mimọ fun Un.
AS-SAMIIHU: Ẹni tí igbọran Rẹ kari gbogbo nnkan, O si n gbọ gbogbo ohun tòun ti bi o ṣe pe oríṣiríṣi.
AL-BASIIR: Ẹni tí O ṣe pe O n ri gbogbo nnkan, O si n ri gbogbo nnkan boya o kere ni tabi o tobi.
AL-HALIIM: Oun ni imọ Rẹ kari gbogbo nnkan lori ohun ti o ti lọ tabi ti n ṣẹlẹ lọwọ tabi ti yoo pada ṣẹlẹ lọjọ iwaju.
AR-RAHMAAN: Ẹni tí O ṣe pe ikẹ Rẹ kari gbogbo ẹda Rẹ ati gbogbo nǹkan ti n ṣẹmi, gbogbo ẹrusin ati ẹda ni n bẹ labẹ ikẹ Rẹ.
AR-ROZZAAQ: Ọba ti ijẹẹmu gbogbo ẹda ninu eeyan, alijannu ati gbogbo ẹranko n bẹ ni ọwọ Rẹ.
AL-HAYY: Alaaye ti ko nii ku, gbogbo ẹda ni yoo si ku.
"Ọba Ńlá:
Ẹni ti O jẹ pe gbogbo pipe nbẹ fun Un ati gbogbo titobi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ."

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinlelọgbọn: Ki ni ojuṣe wa si awọn onimimọ musulumi? "

"Idahun- a maa nífẹ̀ẹ́ wọn, a maa ṣẹri pada si ọdọ wọn nipa awọn àlámọ̀rí ati awọn iṣẹlẹ ọtun ti sharia, ki a ma darukọ wọn afi pẹlu daada, ẹnikẹ́ni ti o ba darukọ wọn pẹlu nnkan miiran to yatọ si iyẹn ninu aburu; ko si ni oju-ọna. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ 11} [Suuratul-Mujadila 11].

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogoji: Ta ni awọn ọrẹ ayo Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-? "

"Idahun- awọn ni onigbagbọ olubẹru. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé) 62 (Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu) 63} " [Suuratu Yunus: 62, 63].

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlogoji: Ǹjẹ́ igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ bí? "

"Idahun- igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlogoji: Ǹjẹ́ igbagbọ a maa lekun a si tun maa dínkù? "

"Idahun- igbagbọ maa n lekun pẹlu itẹle a si maa dínkù pẹlu ẹṣẹ. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé 2} " "[Surah Al-Anfâl: 2]"

"Ibeere ẹlẹẹkejidinlogoji: Ki ni dáadáa? "

"Idahun- ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba ri I; dajudaju Oun n ri ẹ. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkandinlogoji: Ìgbà wo ni awọn iṣẹ yio di itẹwọgba lọdọ Ọlọhun -mimọ ni fun Un-?"

"Idahun- pẹlu majẹmu meji: "
"1- ti o ba mọ́ kangá nitori ojú rere Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
"2- Ti o ba jẹ lori oju-ọna Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "

"Ibeere ogoji: Ki ni igbarale Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "

"Ibeere ogoji: Ki ni igbarale Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o } "[Surah At-Talâq: 3]"
"{Hasbuhu} : tabi O maa to fun un. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkanlelogoji: Ki ni nǹkan to n jẹ ojúṣe pipaṣe dáadáa ati kíkọ ohun buruku? "

"Idahun- AL’MAHRUUF: Oun ni pipaṣe lati ṣe gbogbo itẹle Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, AL-MUNKAR: Oun ni kikọ kuro nibi gbogbo ṣiṣẹ Ọlọhun Alagbara ti O gbọnngbọn.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Ẹ jẹ́ ìjọ t’ó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu } "[Surah Âl-`Imrân: 110]"

"Ibeere ẹlẹẹkejilelogoji: Àwọn wo ni Ahlus Sunna Wal Jamaa’ah?"

"Idahun- awọn ni awọn to wa lori nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lori ẹ ati awọn sàábé rẹ nibi ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan. "
"Wọn sọ wọn ni oni sunnah:
Torí itẹle wọn ti wọn n tẹle oju-ọna Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati gbigbe adadaalẹ ju silẹ. "
"Wal Jamaa'ah:
Torí pe wọn kojọ lori ododo ti wọn ko si yapa nibẹ.

"Abala imọ agboye ẹṣin "47

"Ibeere kini: Ṣàlàyé imọra?"

"Imọra: Oun ni gbigbe ẹgbin ti a ko le fi ojú ri, ati ẹgbin ti a le fi ojú ri"
"Mimọ ẹgbin ti a le fi ojú ri:
Oun ni ki musulumi mu nnkan ti o wa ni ara rẹ ninu ẹgbin kuro, tabi to wa ni aṣọ rẹ, tabi to wa lori ilẹ ati aye ti o fẹ kirun nibẹ. "
"Mimọ ẹgbin ti a ko le fi ojú ri:
Oun maa jẹ pẹlu aluwala tabi iwẹ, pẹlu omi ti o mọ tabi imọra oni erupẹ fun ẹni ti ko ri omi, tabi ti lilo ẹ ni i lara. "

"Ibeere keji: Báwo ni a ṣe maa mọ nnkan ti ẹgbin ba wa lara ẹ? "

"Idahun- pẹlu fifọ ọ pẹlu omi titi o fi maa mọ "
"-Sugbọn nnkan ti aja ba ti ẹnu bọ; a maa fọ ọ ni ẹẹmeje ti àkọ́kọ́ maa jẹ pẹlu erupẹ. "

"Ibeere kẹta: Ki ni ọla ti o wa fun aluwala? "

"Anabi -ki ikẹ ati ọla maa ba a- sọ pe: “Ti musulumi ba ṣe aluwala, tabi olugbagbọ, ti o wa fọ oju rẹ; gbogbo ẹṣẹ ti o fi oju rẹ wo a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, ti o ba fọ ọwọ rẹ mejeeji; gbogbo ẹṣẹ ti o fi ọwọ rẹ mejeeji gbamu a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, ti o ba fọ ẹsẹ rẹ mejeeji; gbogbo ẹṣẹ ti o fi ẹsẹ rẹ mejeeji rin lọ sibẹ a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, titi yoo fi jade ni ẹni ti o mọ kuro nibi awọn ẹṣẹ” Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere kẹrin: Báwo ni waa ṣe ṣe aluwala? "

"Idahun- fifọ ọwọ lẹẹmẹta "
"Waa fi omi yọ ẹnu, waa si fa omi si imu, waa si fin omi si ita lẹẹmẹta."
AL-MADMADỌ ni: Fífi omi si ẹnu, ati titu u sita"
AL-ISTINSHAAQ: Fífa omi pẹlu atẹgun lọ si inu imu pẹlu ọwọ ọtun rẹ."
AL-ISTINTHAAR: Oun ni mimu omi jade lati inu imu lẹyin fifa a simu pẹlu ọwọ osi.
"Lẹyin naa ni fifọ oju lẹẹmẹta. "
"Lẹyin naa ni fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji lẹẹmẹta"
"Lẹyin naa ni pipa ori lọ si iwaju pẹlu ọwọ rẹ mejeeji ati lọ si ẹyin, waa si pa eti mejeeji."
"Lẹyin naa waa fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji lẹẹmẹta "
"Eleyii ni eyi ti o pe julọ, iyẹn si fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn hadisi ninu Bukhari ati Muslim, ti awọn mejeeji gba a wa lati ọdọ Uthman ati Abdulahi Bn Zaid ati awọn to yatọ si awọn mejeeji, " O tun fi ẹsẹ rinlẹ bakannaa lati ọdọ rẹ ninu Bukhari ati ẹni ti o yatọ si i pe o ṣe aluwala ni ẹyọ kọọkan, ati pe o ṣe e ni ẹẹmeji meji pẹlu itumọ pe: O n fọ gbogbo oríkèé kọọkan ninu awọn oríkèé aluwala lẹẹkan, tabi lẹẹmeji. "

"Ibeere karun-un: Ki ni awọn ọranyan aluwala, ati onka wọn? "

"Idahun- Oun ni eyi ti aluwala musulumi ko nii ni alaafia ti o ba gbe ẹyọkan ju silẹ ninu ẹ. "
"1- Fifọ oju ti yiyọ ẹnu ati fifa omi si imu n bẹ ninu ẹ. "
"2- Fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji. "
"3- Pipa ori ti eti mejeeji n bẹ ninu ẹ
"4- Fifọ ẹsẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji. "
"5- Tito tẹle ara wọn laarin awọn oríkèé, pẹlu pe ki o fọ oju, lẹyin naa ọwọ mejeeji, lẹyin naa pipa ori, lẹyin naa fifọ ẹsẹ mejeeji. "
"6- Isopọ: Oun ni ki aluwala waye ni asiko to sopọ mọ ara wọn, laisi alagata laarin asiko titi awọn oríkèé o fi gbẹ fun omi"
"- Gẹgẹ bii ki o ṣe idaji aluwala, ki o wa pari ẹ ni asiko miiran, aluwala rẹ o ni alaafia. "

"Ibeere kẹfa: Ki ni awọn sunnah aluwala, ati onka wọn? "

"Idahun- awọn sunnah aluwala” ni eyi to jẹ pe ti o ba ṣe e, alekun ninu ẹsan o maa bẹ fun un, ti o ba gbe e ju silẹ; ko si ẹṣẹ fun un, aluwala rẹ ni alaafia. "
1- Didarukọ Ọlọhun: mo bẹrẹ pẹlu orukọ Ọlọhun.
2- Rirun pako
3- Fifọ ọwọ mejeeji.
4- Fifi ọwọ ya awọn ọmọnika
5- Fifọ oríkèé ara ẹlẹẹkeji ati ẹlẹẹkẹta.
6- Bibẹrẹ pẹlu ọtun
7- Ṣíṣe iranti lẹyin aluwala: Ash’hadu an laa ilaaha illal Loohu, wahdahuu laa shariika lahuu, wa ash’hadu anna Muhammadan abduhuu wa rosuuluhuu
8- Kiki irun rakah meji lẹyin rẹ.

Ibeere keje: Ki ni awọn onka ohun ti o maa n ba aluwala jẹ?

Idahun- Ohun ti n jade lati oju ara mejeeji; oju ara ati oju idi bii itọ abi igbẹ abi iso.
Oorun ati yiya were ati hihunrira
Jijẹ ẹran rakunmi.
Gbigba oju-ara abi idi mu pẹlu ọwọ laisi gaga kankan.

Ki ni Tayammum?

Idahun- Tayammum: Oun ni lilo erupẹ abi nnkan miran ni ori ilẹ nigba ti ko ba si omi abi ti ko ba rọrùn lati lo o.

Ibeere kẹsàn-án: Bawo ni waa ṣe ṣe Tayammum?

Idahun- Fifi oju ọwọ lu ilẹ ni lilu ẹẹkan ṣoṣo, ati pipa oju ati ẹyin ọwọ méjèèjì ni ẹẹkan ṣoṣo.

Ìbéèrè kẹwaa: Ki ni awọn nnkan ti o le ba Tayammum jẹ?

Idahun- Gbogbo ohun ti o ba ti le ba aluwala jẹ.
Ti wọn ba ri omi

Ibeere kọkànlá: Ki ni wọn n pe ni khuffu ati ibọsẹ? Njẹ yoo pa awọn mejeeji?

Idahun- Khuffu mejeeji: Ni ohun ti wọn ba n wọ si ẹsẹ ti wọn ṣe latara awọ.
Ibọsẹ:
Ohun ti wọn ba n wọ si ẹsẹ ti kii ṣe latara awọ.
Wọn ṣe e ni ofin lati pa awọn mejeeji ni ifirọpo fifọ ẹsẹ mejeeji.

Ibeere 12 - Darukọ ọgbọn ti n bẹ nibi pipa khuffi (abọsẹsẹ alawọ) mejeeji?

Idahun - ṣiṣe idẹkun ati ṣiṣe ẹdẹ fun awọn ẹrusin, agaga julọ ni awọn asiko otutu ati ọyẹ ati irin-ajo, l'eyiti o ṣe wipe bibọ nkan ti o wa ni ẹsẹ mejeeji maa nira.

Ibeere 13 – Kí ni awọn majẹmu nini alaafia pipa khuffi (abọsẹsẹ alawọ) mejeeji?

Idahun - 1 - ki o wọ abọsẹsẹ alawọ mejeeji lori imọra, itumọ rẹ ni lẹyin aluwala.
2- Ki abọsẹsẹ alawọ o jẹ nǹkan ti o mọ; nitori naa ko lẹ́tọ̀ọ́ ki o pa a lori ẹgbin.
3- Ki abọsẹsẹ alawọ jẹ nkan ti o bo aaye ti fifọ rẹ jẹ dandan nibi aluwala.
4- Ki pipa naa o jẹ laarin asiko ti a ti fi gbedeke sí, fun ẹniti o wa ni ile ti kii ṣe arinrin-ajo: Ọjọ kan ati oru kan, fun arìnrìn-àjò: Ọjọ mẹta pẹlu àwọn oru wọn.

Ibeere 14- Ki ni iroyin (alaye) pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji?

Nípa iroyin (alaye) pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji oun naa ni: Ki o gbe awọn ọmọnika ọwọ rẹ mejeeji eleyii ti o ti tutu rẹ pẹlu omi lori awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji, lẹyin naa ki o wọ́ mejeeji lọ sibi ojúgun rẹ, yio pa ẹsẹ ọtun pẹlu ọwọ ọtún, yio si pa ẹsẹ osi pẹlu ọwọ osi, yio si ya awọn ọmọnika rẹ nígbà tí o ba n pa a, ko si nii paara rẹ.

Ibeere 15- Ki ni nkan ti o maa n ba pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji jẹ?

Idahun-1- Pipari asiko pipa, nitori naa pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji o lẹ́tọ̀ọ́ lẹyin pipari asiko pipa tí a ti paala rẹ ninu sheriah (ofin ẹsin), ọjọ kan ati oru kan fun ẹniti n bẹ nile, ati ọjọ mẹta pẹlu awọn oru wọn fun arìnrìn-àjò.
2- Bibọ abọsẹsẹ alawọ mejeeji, ti ọmọnìyàn ba ti le bọ́ abọsẹsẹ alawọ mejeeji tabi ọkan ninu wọn lẹyin ti o ti pa a, pipa mejeeji ti bajẹ.

Ibeere 16- Itumọ Irun?

Idahun- Irun: Oun ni ṣiṣe ijọsin fun Ọlọhun pẹlu awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ti wọn sa l'ẹsa, ti o bẹrẹ pẹlu ki kabara (gbigbe titobi fun Ọlọhun), ti o si pari pẹlu sí salamọ.

Ibeere 17: Idajọ Irun?

Idahun- Irun ọranyan lo jẹ lori gbogbo Musulumi.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴾Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo 103﴿ [Sūratun Nisā‘i: 103].

Ibeere 18: Ki ni idajọ gbigbe Irun ju silẹ?

Idahun- Gbigbe Irun ju silẹ iṣe keferi ni, Anabi - kí ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe: «Adehun ti n bẹ laarin wa ati laarin wọn (awọn keferi) ni Irun, ẹniti o ba wa gbe Irun ju silẹ ti di keferi». Ahmad ati Tirimidhi ati awọn mii yatọ si awọn mejeeji ni wọ́n gba a wa.

Ibeere 19- Irun mélòó lo jẹ dandan lori Musulumi ni ojumọ (aarọ ati alẹ)? Melo si ni awọn onka Irun kọọkan?

Idahun- Irun márùn-ún ni ni ojumọ (aarọ ati alẹ), Irun Al-fajri: Rakah meji, Irun Dhuri: Rakah mẹẹrin, Irun Asri: Rakah mẹẹrin, Irun Magrib: Rakah mẹta, Irun Ishai: Rakah mẹẹrin.

Ibeere 20: Onka awọn majẹmu Irun?

Idahun- 1- Isilaamu; ko (Irun) si nii ni alaafia lati ọdọ keferi.
2- Laakaye: ko si nii ni alaafia lati ọdọ weere.
3- Isẹ adayanri; ko si nii ni alaafia lati ọdọ ọmọde ti ko i tii le ṣe adayanri.
4- Aniyan.
5- Wíwọlé asiko.
6- Imọra nibi mímú ẹgbin aifojuri kúrò.
7- Imọra kuro nibi idọti (ẹgbin afojuri).
8- Bibo ihoho.
9- Didaju kọ Qiblah.

Ibeere 21: Onka awọn origun Irun?

Idahun- Mẹrinla ni i, gẹ́gẹ́ bí o ṣe n bọ̀ yii:
Akọkọ rẹ: Diduro níbi Irun ọranyan fun ẹniti o ni ikapa.
Kabara imura, oun naa ni: “Allāhu Akbar”.
Kika Fātiah.
Itẹkọkọ, yio wàá na ẹyin rẹ tọọ ti yio si gbe ori rẹ si deedee rẹ.
Gbigbe ori kuro nibẹ (Itẹkọkọ).
Diduro dede.
Iforikanlẹ, gbigbe iwaju ori rẹ, ati imu rẹ, ati atẹlẹwọ rẹ mejeeji, ati orunkun rẹ mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji le aaye iforikanlẹ rẹ daadaa.
Gbigbe ori kúrò ni iforikanlẹ.
Ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji.
Sunnah ni:
Ki o jókòó ni ẹniti yio tẹ ẹsẹ osi rẹ silẹ, ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ duro, ti yio si da a kọ Qibla.
Ifarabalẹ, oun naa ni isinmi ara nibi gbogbo orígun ti o jẹ iṣẹ ṣiṣe.
Ataaya Igbẹyin.
Jíjókòó fun un (Ataaya igbẹyin).
Salamọ Mejeeji, oun naa ni ki o sọ ni ẹẹmeji pe: “As salāmu alaykum wa rahmotulloohi wa barakaatuhu”.
Tito awọn orígun tẹle ara wọn- gẹ́gẹ́ bí a ti wi - ti o ba wa fi orikanlẹ ṣíwájú ki o to rukuu lẹniti o mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e; o (Irun) ti bajẹ, ti o ba wa jẹ ti igbagbe; o jẹ dandan fun un pipada lati lọ rukuu, lẹyin naa ki o wa fi ori kanlẹ.

Ibeere 22: Darukọ awọn ọranyan Irun?

Idahun- Awọn ọranyan Irun, mẹjọ ni, gẹ́gẹ́ bí o ṣe n bọ yii:
1- Awọn kabara yàtọ̀ si kabara imura.
2- Gbólóhùn: «Sami‘a Allāhu liman hamidahu» fun imaamu ati ẹniti n da Irun ki.
3- Gbolohun: «Robbanā wa lakal hamdu».
4- Gbolohun: «Subhāna robbiyal ‘adhīm» ni ẹẹkan ni rukuu .
5- Gbolohun: «Subhāna robbiyal ’a‘lā» ni ẹẹkan ni iforikanlẹ.
6- Gbolohun: «Robbi igfir lī» laarin iforikanlẹ mejeeji.
7- Ataaya àkọ́kọ́.
8- Jíjókòó fun ataaya àkọ́kọ́.

Ibeere 23: Ki ni awọn sunnah (aṣegbọrẹ) Irun?

Idahun- Mọkanla ni i, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe n bọ yii:
1- Gbolohun rẹ lẹyin kabara imura pe: «Subhānaka allāhummo wa bi hamdika, wa tabāraka ismuka,wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka» wọn sì tun maa n pe e ni adua ìṣírun.
2- Wiwa iṣọra (Sisọ gbólóhùn "a‘udhu billāhi minash Shaytānir rajīm").
3- Ṣiṣe bismillahi.
4- Gbolohun: Āmīn.
5- Kika Sūrah lẹyin fātiha.
6- Gbigbe ohun soke pẹlu kika fun Imāmu.
7- Sisọ lẹyin gbolohun "Robbanā wa lakal hamdu" pe: «Mil’as Samāwāti, wa mil’al ardi, wa mil’a mā shita min shay'in ba‘d».
8- Ohun ti o ju ẹyọkan lọ nibi ṣiṣe afọmọ ni rukuu, ìyẹn tumọ si: Ṣiṣe afọmọ ẹlẹẹkeji ati ẹlẹẹkẹta, ati ohun ti o ba ju ìyẹn lọ.
9- Ohun ti o ju ẹyọkan lọ nibi ṣiṣe afọmọ iforikanlẹ.
10- Ohun ti o ba ju ẹyọkan lọ nibi gbolohun rẹ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: "Robbi igfir lī".
11- Ṣíṣe asalaatu fun awọn ara-ile rẹ ki alaafia maa ba wọn, ati titọrọ alubarika fun un ati fun wọn, ati ṣiṣe adua lẹyin rẹ.
"Ẹlẹẹkẹrin:
Sunna nibi awọn iṣẹ, ati pe wọn n pe e ni awọn iṣesi: "
"1- Gbigbe ọwọ mejeeji soke pẹlu ki kabara iwọ inu irun. "
"2- Ati nibi rukuu. "
"3- Ati nibi gbígbé orí kuro nibẹ. "
"4- Ati gbígbé mejeeji sílẹ̀ lẹyin iyẹn"
"5- Gbigbe ọtun lori osi. "
"6- Ki o maa wo ààyè ifi-ori-kanlẹ rẹ"
"7- Fífi àlàfo si àárín ẹsẹ rẹ mejeeji ni ẹni ti o duro"
8- Fifi ọwọ rẹ méjèèjì di orunkun rẹ méjèèjì mu ni ẹni tí ó máa ya àwọn ọmọnika nibi rukuu rẹ, ati títẹ́ ẹyin rẹ nibẹ, ati jijẹ ki ori rẹ ṣe déédéé ẹyin rẹ.
Fifi àwọn oríkèé iforikanlẹ kan ilẹ̀ daadaa, ki wọn si lé ilẹ̀ láìsí gàgá kankan.
"10- Mimu ọwọ́ rẹ mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ mejeeji, ati ikun rẹ jina si itan rẹ mejeeji, ati itan rẹ mejeeji jina si ojugun rẹ mejeeji, ati fifi àlàfo si aarin orunkun rẹ mejeeji, ati ninaro ẹsẹ rẹ mejeeji, ati gbigbe awọn inu awọn ọmọ ika ọwọ rẹ mejeeji lori ilẹ ti o maa ya a, ati gbigbe ọwọ rẹ mejeeji si deede ejika rẹ mejeeji pẹlu titẹ awọn ọmọ ika rẹ ti o si maa lẹ àwọn ọmọ-ìka papọ. "
"11- Jíjókòó le ori ẹsẹ nibi ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji, ati nibi ataya àkọ́kọ́, ati fifi idi jókòó nibi ẹlẹẹkeji. "
12- Gbígbé ọwọ méjèèjì lórí itan méjèèjì ni títẹ́ ti àwọn ọmọ-ika si maa wa ni lilẹ papọ láàrin iforikanlẹ méjèèjì, gẹgẹ bẹẹ naa ni nibi ataya, ṣùgbọ́n yoo ka ika kẹrin ati karùn-ún ko, yio ṣe atanpako pẹlu ìka aarin róbótó, yio maa fi ika keji tọka nibi iranti Ọlọhun. "
"13- Yio maa wo ọtun ati osi nibi sisalamọ rẹ. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinlelogun: Onka awọn nnkan ti o n ba irun jẹ? "

"Idahun- (1) gbigbe origun kan tabi majẹmu kan ju silẹ ninu awọn majẹmu irun. "
"(2) Mimọọmọ sọrọ. "
"(3) Jijẹ tabi mimu. "
"(4) Lilọ-bibọ to pọ to tẹle ara wọn. "
(5) Gbigbe ọranyan kan ninu awọn ọranyan irun ju silẹ ni ti amọọmọ ṣe. "

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlọgbọn: Báwo ni musulumi ṣe maa kirun? "

"Idahun- bi a ṣe n kirun: "
"1- Didojukọ qiblah pẹlu gbogbo ara rẹ, láìní yẹ̀ tabi yíjú. "
"2- Lẹyin naa yoo dàníyàn irun ti o fẹ ki pẹlu ọkan rẹ laini wi aniyan naa jáde. "
"3- Lẹyin naa yoo kabara iwọ irun, yio sọ pe: (Allahu Akbar), yio gbe ọwọ rẹ mejeeji soke titi de ejika rẹ mejeeji nibi kikabara. "
4- Lẹyin naa yio gbe atẹlẹwọ ọtun rẹ lori ẹyin atẹlẹwọ osi rẹ lori aya rẹ.
5- Lẹyin naa yio bẹrẹ Irun lẹniti yio maa sọ pe «Allāhumma bā‘id baynī wa bayna khatāyāya kamā bā‘adta baynal mashriq wal Magrib, allāhumma naqqinī min khatāyāya kamā yunnaqqa thaobul abyadu minad danas, allāhumma igsilnī min khatāyāya bil mā’i wath-thalji wal barad».
Tabi ki o sọ pe:
«Subhānaka allāhumma wa bi amdika, wa tabāraka ismuka wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka».
6- lẹyin naa yio wa iṣọra ti yio si maa sọ pe: «A‘ūdhu billāhi minash Shaytānir rajīm». 7- Lẹyin naa yio ṣe bismiLlāhi yio si ka Fātiha ti yio maa sọ pe: "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" 1 "Alhamdulillāhi robbil aalamiin" 2 "Ar-Rahmānir Rahīm" 3 "Māliki yaomid dīn" 4 "Iyyāka na‘budu wa iyyāka nasta‘īn" 5 "Ihdinas Sirātal mustaqiim" 6 "Sirātal Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dālīn" 7 Sūratul Fātiha: 1-7.
Lẹyin naa yio sọ pe:
(Āmīn) itumọ rẹ ni wipe: Irẹ Ọlọhun jẹ ipe.
8- Lẹyin naa yio ka eyikeyi ti o ba rọ ọ lọrun ninu Al-Qur'āni, yio si fa kika nkan gun nibi Irun Subhi".
9- Lẹyin naa yio rukuu, iyẹn tumọ si wipe: Yoo tẹ ẹyin rẹ lati gbe titobi fun Ọlọhun, yio si kabara nígbà tí o ba fẹ rukuu, ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Àti pé sunnah ni: Ki o na ẹyin rẹ, ki o si fi ori rẹ ṣe deedee rẹ, yio si tun gbe ọwọ rẹ mejeeji le orunkun rẹ mejeeji l'ẹniti yio ya awọn ọmọnika ọwọ.
10- Yio si tun sọ nibi rukuu rẹ pe: «Subhāna robbiyal adhīm» ni ẹẹmẹta, ti o ba wa fi kun un pe: "Subhānaka allāhumma wa bi amdik, allāhumma igfir li», ìyẹn náà dáa.
11- Lẹyin naa yio gbe ori rẹ soke lati rukuu lẹniti yio maa sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Ẹniti o jẹ ero ẹyin (ti n kirun lẹyin Imāmu) o nii sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» bi ko ṣe pe yio sọ lati fi jirọ rẹ pe: «Rabbanā walakal amdu»
12- Lẹyin naa yio wa sọ lẹyin ti o ba ti gbe ori soke pe: «Rabbanā wa lakal amdu mil’as samāwāti wal ardi, wa mil’a mā shita min shay’in ba‘d».
13- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ àkọ́kọ́, yio waa maa sọ nígbà tí o ba fẹ fi orikanlẹ rẹ pe: “Allāhu Akbar” ti yio si fi oríkèé ara meje kanlẹ: Iwaju ori ati imu, atẹlẹwọ mejeeji, orunkun mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji, yio si gbe apa rẹ mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ, ko si nii tẹ apa rẹ mejeeji silẹ, ti yio si tun da oju awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji kọ Qibla.
14- Yio waa maa sọ ni iforikanlẹ pe: «Subhāna robbiyal a’lā» ni ẹẹmẹta, ti o ba si tun fi kun un pe: «Subhānaka allāhumma robbāna wa bi amdika, allāhumma igfir lii» o daa.
15- Lẹyin naa yoo gbe ori soke lati iforikanlẹ lẹniti yio maa sọ pe: “Allāhu Akbar”.
16- Lẹyin naa yio jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji lori ẹsẹ osi rẹ ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ, ti yio si gbe ọwọ ọtun rẹ si eti itan rẹ ọtun ti o tẹle orunkun, yio waa ka ìka oruka-yẹmi ati kurumbete kò, yio waa na ìka odun-unlabẹ rẹ soke ti yio si maa mi in nibi adua, ti yio si fi eti atampako rẹ ko eti ogajuwọnlọ gẹ́gẹ́ bíi òrùka róbótó, yio waa gbe ọwọ́ rẹ osi lori eti itan òsì rẹ ti o sunmọ orunkun ni ẹni tí yio tẹ́ awọn ọmọnika rẹ silẹ.
17- Yio si tun sọ nibi ìjókòó rẹ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Robbi igfir lī, warhamnī, wahdinī, warzuqnī, wajburnī, wa ‘āfinī».
18- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ ẹlẹẹkeji gẹgẹ bii àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, yio si kabara nibi iforikanlẹ rẹ.
19- Lẹyin naa yio dide nibi iforikanlẹ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar» yio si ki rakah ẹlẹẹkeji bíi àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, ṣùgbọ́n ko nii sọ adua iṣirun nibẹ.
20- Lẹyin naa yio jókòó ti o ba ti pari raka‘ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», yio si tun jókòó gẹgẹ bi o ṣe jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji gẹlẹ.
21- Yio si ka ataaya nibi ìjókòó yii, ti yio maa sọ pe: At-Tahiyyātu lillāh was sọlawātu wat Tọyyibāt, As-salaamu alayka ayyuhan nabiyyu warahmatulloohi wabarokaatuh, as’salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis soolihiin, ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu, allāhummọ solli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā sollayta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd, wa bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā bārakta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd. ’A‘ūdhu bil Lāhi min ‘adhābi jahannam, wa min ‘adhābil qobri, wa min fitnatil mahyā wal mamāti, wa min fitnatil masīhid dajjāl»
"Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, ọla Ọlọhun ki o maa ba ọ iwọ Anabi ati ikẹ Rẹ ati awọn oore Rẹ, ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa ati gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni ire, mo jẹri wipe ki ẹnití ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, mo sì tun jẹri wipe Muhammad ẹru Rẹ ni òjíṣẹ Rẹ sì ni pẹlu, Iwọ Oluwa wa ṣe ikẹ fún Anabi Muhammad, ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe ikẹ fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi, Oluwa wa ṣe Ìbùkún fún Anabi Muhammad ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe Ìbùkún fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm, dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi" Lẹyin naa yio wa kepe Oluwa rẹ pẹlu nkan ti o ba fẹ ninu oore aye ati ti ọjọ ikẹhin.
22- Lẹyin naa yio waa salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.
23- Ti Irun ba wa jẹ olopoo mẹta tabi mẹẹrin; yio duro nibi ipari ataaya àkọ́kọ́, oun naa ni: «’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu»
24- Lẹyin naa yio waa dide duro l'ẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji nígbà náà.
25- Lẹyin naa yio ki èyí tí o ṣẹku nibi Irun rẹ lori iroyin rakah ẹlẹẹkeji, ṣùgbọ́n Fātiah nikan ni yio ka.
26- Lẹyin naa yio jókòó ni ìjókòó tawarruk, ti yio gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke, yio si yọ ẹsẹ osi rẹ jade labẹ ojugun rẹ ọtun, ti yio si fi idi rẹ le'lẹ dáadáa, yio waa gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan rẹ mejeeji lori iroyin bi o ṣe gbe e nibi ataaya àkọ́kọ́.
27- Yio waa ka gbogbo ataaya nibi ìjókòó yii.
28- Lẹyin naa yio wàá salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe:: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.

Ibeere 26: Ki ni nkan ti waa maa sọ ninu awọn asikiri lẹyin salamọ nibi Irun?

Idahun- «Astagfirullāha» ni ẹẹmẹta.
«Allāhummọ ’Antas Salām, wa minKas salām, tabārakTa, yā Dhal jalāli wal ikrām».
“Laa ilaaha illa laah, Wah'dahu laa shariika lahu, lahul Mulku wa lahul Hamdu Wa uwa ala kulli shaein Qodiir,Allahuma la maaniha lima A'tayta Wa la mu'tiya lima mana'ta wa la yan'fahu zal jaddi Minkal jaddu” (Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti E ni eyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan, Ire Oluwa, ko si oludena fun nkan ti O ba fun ni, atipe ko si olufunni ni ohun ti O ba ko funni atipe oro kole wulo fun oloro ni odo Re).
«Lā ’ilāha ’illāLlāhu wahdahu lā sharīka lahu, lahul mulku wa lahul amdu, wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr, lā haola walā quwwata illā bilLāh, lā ’ilāha ’illāLlāhu, walā na‘budu illā Iyyāhu, laHun ni‘matu wa laHul fadlu wa laHuth thanā’ul hasan, lā ’ilāha ’illāLlāhu mukhlisiina laHud dīn wa lao karihal kāfirūn».
«Subhānallāhi» ni igba mẹtalelọgbọn.
«Alhamdulillāhi» ni igba mẹtalelọgbọn.
«Allāhu Akbar» ni igba mẹtalelọgbọn.
Lẹyin naa yio sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: «Lā ilāha illāLlāhu wahdahu lā sharīka lahu, lahul mulku wa lahul amdu, wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr».
Yio ka Sūratul Ikhlās (qul Uwa Allāhu Ahad) ati Al-Mu‘awwidhāt (qul a‘ūdhu bi robbil falaqi ati qul a‘ūdhu bi robbin nās) ni ẹẹmẹta lẹyin Irun Al-fajri ati Irun Magrib, ati ni ẹẹkan lẹyin awọn Irun yoku.
Yio si tun ka āyatal qursiyyu ni ẹẹkan.

Ibeere 27: Ki ni awọn sunnah (asegbọrẹ) awọn Irun wakati márùn-ún? Kí sì ni ọla ti n bẹ fun un?

Idahun- Raka‘a meji ṣíwájú Al-fajri.
Raka‘a mẹẹrin ṣíwájú irun aila.
Raka‘a meji lẹyin irun aila.
Raka‘a meji lẹyin Magrib.
Raka‘a meji lẹyin Ishai.
Ọla rẹ:
Anabi sọ pe: «Ẹniti o ba ki Raka‘a akigbọrẹ mejila ni ojumọ (aarọ ati alẹ) Ọlọhun maa kọ ile kan fun un ninu ọgba alujanna» Muslim ati Ahmad ati ẹlomiran yatọ si awọn mejeeji ni wọn gba a wa.

Ibeere 28: Ewo lo ni ọla ju ninu awọn ọjọ ọsẹ?

Idahun- Ọjọ Jumu‘ah, Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe: «Dajudaju ninu awọn ọjọ yin to daa julọ ni ọjọ Jumu‘ah, ninu ẹ ni wọn da Ādam, ninu ẹ ni wọn gba ẹmi rẹ, ninu ẹ feere fifun o ti waye, ninu ẹ ni kiku (gbogbo ẹda) o ti waye; nitori naa ẹ pọ ni ṣiṣe assalātu fun mi ninu ẹ; nítorí pé dajudaju wọn yio maa fi assalātu yin han mi» O sọ pe: Wọn sọ pe irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni wọn o ṣe maa fi awọn assalātu wa han ọ ti o si jẹ wipe o ti kẹfun - nkan ti wọn n sọ ni pe o ti jẹra - o wa sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun - ti O biyi ti O si tun gbọnngbọn - ti ṣe awọn ara awọn Anabi Rẹ ni eewọ fun ilẹ». Abu Daūd ati ẹlomiran yatọ si i ni wọ́n gba a wa.

Ibeere 29: Ki ni idajọ Irun Jumu‘a?

Ọranyan ojulowo ni i lori gbogbo Musulumi ti o jẹ ọkunrin ti o ti balaga ti o ni laakaye ti o n bẹ ninu ilu (ti kii ṣe arinrin-ajo).
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴾Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.9﴿ [Sūratul Kāfirūn: 9].

Ibeere 30: Melo ni onka Raka‘a Irun Jumu‘a?

Idahun- Onka Raka‘a Irun Jumu‘a meji ni, ti Imāmu o si gbe ohun s'oke nibẹ, l'eyi ti o ṣe wipe khutubah meji ti a ti mọ o ṣaaju rẹ.

Ibeere 31: Njẹ o lẹ́tọ̀ọ́ lati má ki irun Jimọh bi?

"Idahun- Pipa irun ọjọ jimọh jẹ o lẹ́tọ̀ọ́ afi pẹlu idi kan to jẹ ti sharia, o wa lati ọdọ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: " “Ẹnikẹni ti o ba gbe irun ọjọ jimọh mẹta ju silẹ ni ti ailakakun pẹlu ẹ; Ọlọhun maa fi edidi di ọkan rẹ”. " Abu Daud ati ẹni ti o yatọ si i ni wọn gba a wa"

"Ibeere ẹlẹẹkejilelọgbọn: Dárúkọ awọn sunnah ọjọ jimọh? "

Idahun
"1- Wiwẹ "
"2- Lilo lọfinda"
"3- Wiwọ eyi to daa julọ ninu aṣọ"
"4- Titete lọ si mọsalasi"
"5- Pipọ ni ṣíṣe asalaatu fun Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- "
"6- Kika suratul kahf."
"7- Lilọ si mọsalasi ni ẹni ti o n rin"
"8- Wiwa asiko gbigba adura."

"Ibeere ẹlẹẹkẹtalelọgbọn: Dárúkọ ọla ti o n bẹ fun irun Janmọọn? "

"Idahun- Lati ọdọ Abdulahi ọmọ Umar -ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-, pe Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Irun janmọọn ni ọla ju irun adaki lọ pẹlu ipò mẹtadinlọgbọn”. " Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinlelọgbọn: ki ni irẹlẹ nibi irun? "

"Idahun- oun ni ki ọkàn wà nibẹ, ki ara o sì balẹ.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè 1 " "{Àwọn t’ó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn 2} "[Surah Al-Mu’minûn: 1, 2]"

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogoji: Ṣalaye Zakah? "

"Idahun- oun ni iwọ kan to jẹ dandan nibi dúkìá kan pàtó, fun àwọn kan pàtó, ni asiko kan pàtó.
Origun kan ni in ninu awọn origun Isilaamu, saara ti o jẹ ọranyan si tun ni in ti wọn gbọdọ yọ lọwọ eeyan abọrọ ti wọn o si ko o fun alaini.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
Ẹ yọ Zakāh. [Suuratul-Baqarah: 43].

Ibeere kẹrindinlogoji: Ki ni wọn n pe ni saara ti a fẹ?

Idahun: Oun yatọ si Zakah, gẹgẹ bii: Ṣíṣe saara pẹlu èyíkéyìí nǹkan si àwọn ọna oore ni eyikeyii akoko.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Ẹ nawo si oju ọna Ọlọhun}. [Suuratul-Baqarah: 195].

Ibeere kẹtadinlọgbọn: Sọ itumọ Aawẹ gbigba?

Idahun: Oun ni ṣiṣe ijọsin fun Ọlọhun pẹlu kikoraro kuro nibi ohun ti o le ba aawẹ jẹ lati igba ti alufajari ba ti yọ titi di igba ti oorun yoo fi wọ pẹlu dida aniyan, o si ni iran meji:
Aawẹ ọranyan: Bii gbigba aawẹ oṣu Ramadan, o si jẹ origun kan ninu awọn origun Isilaamu.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu). 183 [Suuratul-Baqarah: 183].
Aawẹ ti kii ṣe ọranyan:
Gẹ́gẹ́ bii gbigba aawẹ ọjọ aje ati ọjọbọ ni gbogbo ọsẹ, ati gbigba aawẹ ọjọ mẹta ni gbogbo oṣu, awọn ọjọ ti o si lọla ju ninu rẹ naa ni (13, 14, 15) ni gbogbo oṣu oju ọrun.

Ibeere kejidinlogoji: Darukọ ọla ti n bẹ fun gbigba awẹ oṣu Ramadan?

Idahun- Lati ọdọ Abu Hurairah (ki Ọlọhun yọnu si i), dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: Ẹnikẹni ti o gba aawẹ Ramadan pẹlu igbagbọ ati ni ẹni tí ń rankan ẹsan lọdọ Ọlọhun; wọn yoo ṣe aforijin ohun ti o ti lọ ninu ẹṣẹ rẹ. Wọn fi ẹnu ko le e lori.

Ibeere kọkandinlogoji: Darukọ ọla ti n bẹ fun gbigba aawẹ aṣegbọrẹ ni awọn oṣu ti kii ṣe Ramadan?

Idahun- Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khud'riy (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: Ko si ẹru kankan ti yoo gba aawẹ ọjọ kan ni oju ọna Ọlọhun ayafi ki Ọlọhun titori rẹ gbe oju rẹ jina si ina ni dedee aadọrin ọdun Wọn fi ẹnu ko le e lori.
Itumọ “aadọrin Khareef”; iyẹn ni pe: Aadọrin ọdun.

Ibeere ogójì: Darukọ apa kan ninu awọn nnkan ti o le ba aawẹ jẹ?

Idahun- 1- Mimọọmọ jẹun ati mimọọmọ mu.
2- Mimọọmọ bi.
3- Kikuro ninu Isilaamu.

Ìbéèrè kọkanlelogoji: Ki ni awọn sunnah aawẹ gbigba?

Idahun- 1- Yiyara ṣinu
2- Saari jijẹ ati lilọ ọ lara.
3- Nini alekun lori awọn iṣẹ rere ati ijọsin.
4- Ki alaawẹ sọ nigba ti wọn ba bu u pe: Alaawẹ ni mi.
5- Ṣiṣe adua nigba ti a ba fẹ ṣinu.
6- Fifi eso dabinu tutu abi gbigbẹ ṣinu, ti ko ba si; ni o too kan omi.

Ìbéèrè kejilelogoji: Sọ itumọ Hajj?

Idahun- Hajj: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun Ọba ti O ga pẹlu ero lilọ si ile Rẹ abeewọ lati ṣe awọn iṣẹ kan pàtó ni asiko kan pàtó.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá. 97} [Suuratul Aal Im'raan: 97]

Ibeere kẹtalelogoji: Mélòó ni awọn origun Hajj?

Idahun- 1 - Gbigbe aṣọ áràmí wọ.
2 - Diduro si oke arafa
3 – Tawaaful Ifaadọ.
4 - Sisa safa ati mar'wa

Ibeere kẹrinlelogoji: Ki ni ọla ti n bẹ fun Hajj?

Idahun- Lati ọdọ Abu Huraira (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ẹni tí o ba ṣe hajj nitori Ọlọhun ti ko ba iyawo rẹ sun oorun ìfẹ́, ti ko si dá ẹ̀ṣẹ̀; yoo pada gẹgẹ bi ọjọ ti iya Rẹ bi i. Bukhaari ati awọn ẹlomiran ni wọ́n gba a wa.
«Gẹgẹ bii ọjọ ti iya rẹ bi i»: itumọ rẹ ni pe lai ni ẹṣẹ kankan.

Ibeere 45: Salaye ‘Umrah?

Idahun- ‘Umrah: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - pẹlu gbigbero ile Rẹ abọwọ fun awọn iṣẹ kan ti wọn jẹ ẹsa ni eyikeyi akoko.

Ibeere 46: Onka awọn origun ‘Umrah?

Idahun -1- Gbigbe Harami.
3- Rirọkirika ile Ọlọhun.
3- Sísá Safa ati Marwa.

Ibeere 47: Ki ni a n pe ni ijagun si oju-ọna Ọlọhun?

Idahun- Oun naa ni nina igbiyanju ati ikapa si ibi titan Isilāmu ka ati dida aabo bo o ati awọn Musulumi, tabi biba ọta Isilaamu ati awọn Mùsùlùmí jagun.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
﴾Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀. 41﴿ [Suuratu At-Tawbah: 41].

Ipin Itan Anabi.32

Ibeere 1: Ki ni ìdílé Anabi wa Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Oun ni Muhammad ọmọ Abdullah ọmọ Abdul Muttalib ọmọ Hāshim, ti Hāshim wa lati idile Quraysh, ti Quraysh wa lati iran larubawa, ti larubawa si jẹ arọmọdọmọ Ismā‘īl ti Ismā‘īl si jẹ ọmọ Ibrāhīm, ki ikẹ ati ọla ti o lọla julọ maa ba oun ati Anabi wa.

Ibeere 2: Ki ni orukọ iya Anabi wa (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Āminatu ọmọ Wahb.

Ibeere 3: Ìgbà wo ni baba rẹ ku?

Idahun- Baba rẹ ku ni Mẹdina, ti oun si wa ni oyún, ti wọn o tii bi i (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).

Ibeere 4: Ìgbà wo ni wọn bi Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Idahun- Ni ọdún eleerin, ni ọjọ Monday (aje) ninu oṣù Rabī‘ul awwal.

Ibeere 5: Ilu wo ni wọn ti bi i?

Idahun- Ni Mẹka.

Ibeere 6: Awọn wo ni awọn ti wọn fun un ni ọyàn ati awọn ti wọn tọju rẹ lẹyin iya rẹ.

Idahun- Ẹrubinrin ti baba rẹ sọ di ọmọluabi ti n jẹ Ummu Ayman.
- Ẹrubinrin ti ọmọ-ìyá baba rẹ Abū Lahab sọ di ọmọluabi ti n jẹ Thuwaybah.
- Halīmatu As-Sa‘diyyah.

Ibeere 7: Ìgbà wo ni ìyá rẹ ku?

Idahun- Iya rẹ ku nígbà tí o wa ni ọmọ ọdun meji, ti baba baba rẹ Abdul Muttalib si gba a tọ.

Ibeere 8: Ta ni o gba a tọ lẹyin iku baba baba rẹ Abdul Muttalib?

Idahun- Baba baba rẹ ti n ṣe Abdul Muttalib ku nígbà tí o wa ni ọmọ ọdun mẹjọ, ti ọmọ-ìyá baba rẹ Abū Tālib si gba a tọ.

Ibeere 9: Ìgbà wo ni o ṣe irin-ajo pẹlu ọmọ-ìyá baba rẹ lọ si ilu Shām?

Idahun- O ṣe irin-ajo pẹlu ọmọ-ìyá baba rẹ lọ si Shām ti ọjọ ori rẹ si jẹ ọdun mejila.

Ibeere 10: Ìgbà wo ni irin-ajo rẹ eleekeji wáyé?

Idahun- Irin-ajo rẹ ẹlẹẹkeji wáyé nipa òwò kan ti o ṣe pẹlu owó Khadījah - ki Ọlọhun yọnu si i -, nígbà tí o wa ṣẹri pada, o- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa fẹ ẹ (Khadījah).

Ibeere 11: Ìgbà wo ni awọn Quraysh tun Ka‘bah mọ?

Idahun- Awọn Quraysh tun Ka‘bah mọ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdun marunlelọgbọn.
Wọn si fi ṣe adajọ nígbà tí wọn yapa nipa ẹniti yio gbe okuta dudu si aaye rẹ, ni o wa gbe e si inu aṣọ, o wa pa idile kọọkan laṣẹ ki wọn mu eti kọọkan nibi aṣọ náà, ti wọn si jẹ idile mẹẹrin, nígbà tí wọn wa gbe e de aaye rẹ, o fi ọwọ rẹ gbe e si ibẹ (ki ikẹ ati ọla maa ba a).

Ibeere 12: Ọmọ ọdun melo ni i nígbà tí wọn gbe e dide? Ta ni wọn si ran an si?

Idahun- Ọjọ ori rẹ jẹ ogoji ọdun, wọn si gbe e dide si gbogbo eeyan patapata ni Olufunni niroo idunnu ati olukilọ iya fun ni.

Ibeere 13: Ki ni akọkọ nkan ti Wahyi (Imisi) bẹrẹ pẹlu rẹ?

Idahun- Ala ododo, ko waa nii la ala kankan ayaafi ki o wa gẹgẹ bii imọlẹ owurọ.

Ibeere 14: Bawo ni ìṣesí rẹ ṣíwájú Wahyi (Imisi)? Àti pé ìgbà wo ni Wahyi sọkalẹ fun un ni igba akọkọ?

Idahun- O jẹ ẹni tí maa n ṣe ijọsin fun Ọlọhun ninu kòtò Hirā ti o si maa mú èsè dání fun un.
Wahyi (imisi) si sọkalẹ fun un, nígbà tí o wa nínú koto naa lẹniti n ṣe ijọsin.

Ibeere 15: Kí ni akọkọ nkan ti Ọlọhun sọkalẹ ninu Al-Qur'āni?

Idahun- Gbolohun Ọba ti ọla Rẹ ga pe: Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. 1 Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì. 2 Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ. 3 Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn. 4 Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n. 5 [Suuratul Alaq: 1 - 5]

Ibeere 16: Ta ni ẹni akọkọ ti o ni igbagbọ si iranṣẹ rẹ?

Idahun: Nínú awọn ọkunrin: Abubakr' As-sideeq, ninu awọn obinrin: Khadijah ọmọ Khuwaylid, ninu awọn ọmọ keekeeke: Aliyy ọmọ Abuu Taalib, ninu awọn ẹru ti o ti di ọmọ: Zaid ọmọ Haaritha, ninu awọn ẹru: Bilaal Al-Habashiy (ki Ọlọhun yọnu si wọn) ati awọn miran.

Ibeere 17: Bawo ni ipepe sinu Isilaamu ṣe waye?

Idahun: Ipepe waye ni kọkọ fun nǹkan bíi ọdún mẹta, lẹyin naa ni o (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) paṣẹ pẹlu ipepe gbangba.

Ibeere 18: Kí ni iṣesi Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ati awọn ti wọn gba a gbọ wa lẹyin ti ipepe gbangba waye?

Idahun – Àwọn ọṣẹbọ fi ṣuta kan an gan ati awọn Musulumi, titi ti o fi yọnda fun awọn olugbagbọ ododo lati ṣe hijira lọ si ọdọ Najaashi ni ilẹ Habasha.
Awọn ẹlẹbọ si fi ẹnu kò lati fi ṣuta kan an, ati lati pa a (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a). Ọlọhun wa dáàbò bo o, ti O si rọgbayika rẹ pẹlu ẹgbọn baba rẹ tii ṣe Abuu Taalib lati le baa daabo bo o kuro lọwọ wọn.

Ibeere 19: Ta ni ẹniti o ku ni ọdun ẹlẹẹkẹwaa lati igba ti wọn ti gbe e (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) dide?

Idahun- Ẹgbọn baba rẹ tii ṣe Abuu Taalib ati iyawo rẹ tii ṣe Khadeejah (ki Ọlọhun yọnu si i) kú.

Ibeere 20: Igba wo ni Israa' ati Mi'raaj waye?

Idahun: O wa ni ọmọ ọdun àádọ́ta. Ọlọhun si ṣe awọn irun márùn-ún ni ọranyan le e lori.
Idahun:
Israa': Lati Mọṣalaṣi abeewọ lọ si Mọṣalaṣi Aq'saa.
Mi'raaj:
Oun waye lati Mọṣalaṣi Aq'saah titi lọ si Sid'ratil mun'taha.

Idahun 21: Bawo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ṣe n pe awọn eeyan ni ita makkah.

Idahun: O maa n ṣe ipepe fun awọn ara ilẹ Taaif, o si maa n fi ara rẹ han wọn ni àwọn aaye ipadepọ awọn eeyan titi ti awọn Ansọọr fi de lati ilu Mẹdina ti wọn si gba a gbọ, wọn si tun gba ọwọ rẹ ni ti adehun lati ran an lọ́wọ́.

Ibeere 22: Igba melo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) fi wa ni Mẹka ti n pe awọn eeyan?

Idahun- O lo ọdun mẹtala nibẹ.

Ibeere 23: Nibo ni Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ṣe hijira lọ?

Idahun: O ṣe e lati Makkah lọ si Mẹdina.

Ibeere 24: Igba melo ni o lo ni Mẹdina?

Idahun: Ọdun mẹ́wàá ni in.

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlọgbọn: Ki ni nnkan ti wọn ṣe ni ọranyan le e lori ni Mẹdina ninu awọn ofin Isilaamu? "

"Idahun- wọn ṣe yiyọ zakah ni ọranyan le e lori, ati aawẹ gbigba, ati lilọ si ile oluwa, ati jijagun si oju-ọna Ọlọhun, ati pipe irun, ati eyi to yatọ si i ninu awọn ofin Isilaamu.

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlọgbọn: Ki ni awọn to pataki ninu awọn ogun rẹ ti o kopa nibẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-? "

"Idahun- ogun badari nla."
."Ogun uhud."
"Ogun Al-Ahzâb "
Ogun ṣiṣi Mẹka"

"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlọgbọn: ki ni eyi to kẹyin ninu nnkan ti wọn sọkalẹ ninu Kuraani? "

"Idahun- ọrọ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn 281}. " [Suuratul-Baqarah: 281].

"Ibeere ẹlẹẹkejidinlọgbọn: Ìgbà wo ni Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kú? Ati pe mélòó ni ọjọ ori rẹ? "

"Idahun- o ku ni oṣu Robii’ul Awwal, ni ọdun ẹlẹẹkọkanla ni ọdun hijra, ti o si jẹ ọmọ ọdún mẹtalelọgọta.

"Ibeere ẹlẹẹkọkandinlọgbọn: Dárúkọ awọn iyawo Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ? "

"1- Khadijah ọmọ Khuwailid -ki Ọlọhun yọnu si i- "
"2- Saodah ọmọ Zam'ah- ki Ọlọhun yọnu si i- "
"3- A'ishah ọmọ Abu Bakr -ki Ọlọhun yọnu si i- "
4- Hafsoh ọmọ Umar -ki Ọlọhun yọnu si i- "
"5- Zainab ọmọ Khuzaimoh -ki Ọlọhun yọnu si i- "
"6- Ummu Salamoh Hind ọmọ Abu Umayyah- ki Ọlọhun yọnu si i- "
"7- Ummu Habibah Romlah ọmọ Abu Sufyan- ki Ọlọhun yọnu si i- "
"8- Juwayriyah ọmọ Harith- ki Ọlọhun yọnu si i- "
"9- Maimuunah ọmọ Haarith- ki Ọlọhun yọnu si i- "
10- Sofiyyah ọmọ Hayiy- ki Ọlọhun yọnu si i- "
"11- Zainab ọmọ Jahsh- ki Ọlọhun yọnu si i-"

Ibeere 30: Awọn wo ni awọn ọmọ rẹ (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)?

Awọn ọkunrin mẹta ni wọn:
Qāsim, oun si ni wọn fi maa n da a pe.
Ati Abdullāhi.
Ati Ibrāhīm.
Awọn Obinrin:

Fatima
Rukayyah
Ummu kulthuum
Zaynab
Gbogbo ọmọ rẹ pata, ati ara Khadījah ni wọn ti wa - ki Ọlọhun yọnu si i - ayaafi Ibrāhīm, gbogbo wọn lo si ku ṣaaju rẹ ayaafi Fātimah to ku lẹyin rẹ lẹyin oṣu mẹfa.

Ibeere 31: Darukọ apakan awọn iroyin Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o jẹ ti ṣiṣẹda rẹ?

O jẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹniti o wa ni iwọntun-wọnsi ninu awọn ọkunrin ni, ko kuru ko si ga, amọ o wa laarin iyẹn, o jẹ ẹniti o funfun ti pupa dà papọ mọ ọn - ki ikẹ ati ọla maa ba a- o jẹ ẹniti irungbọn rẹ pọ, ti oju rẹ mejeeji si fẹ̀, ti ẹnu rẹ si tóbi, irun rẹ dudu gan-an, ejika rẹ mejeeji si tóbi, oorun rẹ si dun, ati èyí tí o yatọ si iyẹn ninu ṣiṣẹda rẹ to rẹwa (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)

Ibeere 32: Lori ki ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi awọn ijọ rẹ le?

Idahun- O fi ijọ rẹ silẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sori oju-ọna ti o funfun, ti oru rẹ da bi ọsan rẹ, ẹnikan o si nii yẹ kuro nibẹ ayaafi ẹni iparun, ko si fi daadaa kan silẹ ayaafi ko juwe ijọ rẹ si i, ko si tun fi aburu kan silẹ ayaafi ki o kọ fun wọn kuro nibẹ.

Ipin Tafsīr17

Ibeere 1: Ka Sūratul Fātiha ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Fātiha ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm 1" "Alhamdulillāhi robbil aalamiin 2" "Ar-Rahmānir Rahīm 3" "Māliki yaomid dīn 4" "Iyyāka na‘budu wa Iyyāka nasta‘īn 5" "Ihdinaṣ ṣirātal mistaqīm 6" Sirātọl Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dālīn} Sūratul Fātiha: 1-7.
Alaye
Wọn sọ ọ ni Sūratul Fātiah; latari wipe wọn bẹrẹ iwe Ọlọhun pẹlu rẹ.
🎧 1- {BismiLlāhir Rahmānir Rahīm 1} maa bẹrẹ kika Al-Qur'āni mi pẹlu orukọ Ọlọhun, lẹniti n wa iranwọ pẹlu Rẹ lẹniti n wa alubarika pẹlu orukọ Rẹ.
{Allāhu} itumọ rẹ ni: Ẹniti a maa jọsin fun l'ododo, ati pe wọn ki n pe elomiiran bẹẹ yatọ si I- mimọ n bẹ fun un.
{Ar-Rahmān} itumọ rẹ ni wipe: Oni ikẹ ti o gbaaye ti o kari gbogbo nkan.
{Ar-Rọhīm} itumọ rẹ ni wipe: Ẹniti O ni ikẹ fun awọn Mu’mini.
🎧 {Alhamdulillāhi robbil aalamiin 2} itumọ rẹ ni pe: Gbogbo iran ẹyin ati pipe ti Ọlọhun ni ni Òun nikan soso.
🎧 3- {Ar-Rahmānir Rahīm 3} itumọ rẹ ni pe: Oni ikẹ ti o gbaaye ti o kari gbogbo nkan, Oni ikẹ ti o maa de ọdọ awọn Mu‘mini.
🎧 4- {Māliki yaomid dīn 4}: Oun ni ọjọ igbende.
🎧 5- {Iyyāk na‘budu wa Iyyāk nasta‘īn 5} itumọ rẹ ni pe: A o maa jọsin fun O ni Iwọ nikan a o si tun maa wa iranwọ Rẹ ni Iwọ nikan.
🎧 6- {Ihdinas Sirātal mustaqīm 6}: Oun ni imọna lọ si inu Isilaamu ati Sunnah.
🎧 7- {Sirātọl Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dhālīn 7} itumọ rẹ ni pe: Oju-ọna awọn ẹrusin Rẹ ti wọn jẹ ẹni ire ninu awọn Anabi ati awọn ti wọn tẹle wọn, yatọ si ọna awọn Kristẹni ati awọn Júù.
Wọn si tun ṣe e ni sunnah ki o sọ lẹyin kika a pe:
(Āmīn) itumọ rẹ ni pe: Jẹ ipe wa (da wa loun).

Ibeere 2: Ka Sūratuz Zalzalah ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratuz Zalzalah ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Idhā zulzilatil’ardu zilzālahā 1" "Wa ’akhrajatil ’ardu athqālahā 2" "Wa qālal insānu mālahā 3" "Yaoma idhin tuhaddithu akhbārahā 4" "Bi anna robbaka ’aohālahā 5" "Yaoma idhin yasdurun nāsu ashtātan liyurao ’a‘mālahun 6" "Fa man ya‘mal mithqāla dharratin khoyron yarahu 7" Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i 8}." "[Surah Az-Zalzalah: 1 - 8]
Alaye
🎧 "1- {Izaa zul zilatil ardu zil zaalaha 1}: ti wọn ba mi ilẹ ni mimi to le koko to jẹ wipe yio sẹlẹ si i ni ọjọ igbedide. "
🎧 "2- {Wa akh rajatil ardu athqaalaha 2}: ti ilẹ maa mu nnkan ti o wa ninu ẹ jade ninu awọn oku ati nnkan to yatọ si wọn. "
🎧 3- {Wa qaalal insaanu ma laha 3}: eniyan yo si wi pe ni ẹni ti ọrọ o ye: kini o mu ilẹ ti o n mi ti o si n daru?! "
🎧 4- {Yawmaa izin tuhaddithu akhbaaraha 4}: ni ọjọ nla yẹn ilẹ o ma sọrọ pẹlu nnkan ti wọn ṣe lori ẹ ninu rere ati aburu."
🎧 5- {Bi-anna rabbaka awhaa laha 5}: nitori pe dajudaju Ọlọhun lo fi mọọ ti O si pa a laṣẹ pẹlu iyẹn. "
🎧 "6- {Yawma iziny yas durun naasu ash tatal liyuraw a’maalahum 6}: ni ọjọ nla yẹn, eyi to jẹ pe ilẹ ma mi titi nibẹ, ti eniyan o ma jade lati inu aye iṣiro ni ijọ, lati ri awọn iṣẹ wọn eyi to jẹ pe wọn ṣe e ni ile-aye.
🎧 7- {Famaiy ya’mal mithqala zarratin khai raiy-yarah 7}: ẹni ti o ba ṣe iṣẹ to to odiwọn awurebe kerere ninu awọn iṣẹ rere ati daada, yo ri i ni iwaju rẹ. "
🎧 "8- {Wa maiy-y’amal mithqala zarratin sharraiy-yarah 8}: ẹni ti o ba ṣe iṣẹ ti odiwọn ẹ ninu awọn iṣẹ aburu; yo ri i ni iwaju rẹ. "

"Ibeere kẹta: ka Suratul A'diyah ki o si ṣe alaye ẹ? "

"Idahun- Suratul A'diyah ati alaye ẹ:
Bismillah hir Rahman nir Raheem
{Wal’aadi yaati dabha 1 " "{Fal mooriyaati qadha 2 " "{Fal mugheeraati subha 3 " "{Fa atharna bihii naq’a 4 " "{Fawasatna bihii jam’a 5 " "{Innal-insaana lirabbihii lakanood 6 " "{Wa innahu ‘alaa zaalika la shaheed 7 " {Wa innahu lihubbil khairi la shadeed 8 " "{Afala ya’lamu iza b’uthira ma fil kubuur 9 " "{Wa hussila maa fis suduur 10 " {Inna rabbahum bihim yauma ‘izin lakhabeer 11} " [Sūratul ‘Ādiyāt: 1 - 11].
Alaye:

🎧 1- {Wal ‘ādiyāti dọbhā 1}: Ọlọhun bura pẹlu awọn ẹṣin ti wọn maa n sare debi wipe wọn a maa gbọ ohun eemi wọn latari lile ere sisa naa.
🎧 2- {Fal mūriyāti qad’hā 2}: O si tun bura pẹlu awọn ẹṣin ti awọn patako ẹsẹ wọn maa n sa ina nígbà tí wọn ba tẹ apata látàrí lile titẹ ẹ wọn.
🎧 3- {Fal mugīrāti subhā 3}: O si tun búra pẹlu awọn ẹṣin tii maa n kọlu awọn ọta ni aarọ.
🎧 4- {Fa ’atharna bihi naq‘ā 4}: Ti wọn ta eruku lala pẹlu ere sisa wọn.
🎧 5- {Fa wasatna bihi jam‘ā 5}: Wọn si tun bẹ gija papọ pẹlu awọn afẹsinjagun wọn si aarin awọn ọta.
🎧 6- {Innal insāna li Robbihi la kanūd 6}: Dajudaju ọmọniyan ẹniti maa n kọ daadaa ti Oluwa rẹ n fẹ lati ọdọ rẹ ni.
🎧 7- {Wa innāhu ‘alā dhālika la shahīd 7}: Ati pe dajudaju oun naa n jẹrii lori kikọ daadaa rẹ (ṣiṣe aimoore rẹ).
🎧 8- {Wa innāhu li hubbil khayri la shadīd 8}: Ati pe dajudaju latari ifẹ afẹju rẹ si owo, yio maa ṣe ahun pẹlu rẹ.
🎧 9- {Afalā ya‘lamu izaa bu‘thira mā fil qubūr 9}: Ṣe ọmọniyan ti n gba ẹtan pẹlu isẹmi aye o wa mọ wipe nígbà tí Ọlọhun ba gbe nkan ti o wa ninu ilẹ ni awọn oku jade ti O si tun mu wọn jade lati inu ilẹ fun iṣiro ati ẹsan wipe dajudaju alamọri naa ko ri bi oun ṣe n ro o?.
🎧 10- {Wa hussila mā fis suduur 10}: Wọn o ṣe afihan gbogbo nkan ti o wa ninu awọn ọkan ni awọn erongba ati awọn adisọkan ati nkan miran yatọ si i.
🎧 11- {Inna Rọbbahum bihim yaoma’idhin la khabīr 11}: Dajudaju Oluwa wọn ni Alamọtan nipa wọn ni ọjọ yẹn, ti nkankan o si nii pamọ fun un ninu alamọri awọn ẹru Rẹ, ti Yio si san wọn ni ẹsan lori iyẹn.

Ibeere 4: Ka Sūratul Qāri‘ah ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Qāri‘ah ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"Al-Qāri‘ah 1" "Mal qāri‘ah 2" "Wa mā adrāka mal qāri‘ah 3" "Yaoma yakūnun nāsu kal farāshil mabthūth 4" "Wa takūnul jibālu kal ‘ihnil manfūsh 5" "Fa ammā man thaqulat mawāzīnuhu 6" "Fa huwa fī ‘īshatin rādiyah 7" "Wa ammā man khaffat mawāzīnuhu 8" "Fa ummuhu hāwiyah 9" "Wa mā adrāka mā hiyah 10" "Nārun hāmiyah 11} [Sūratul Qāri‘ah: 1 - 11].
Alaye:

🎧 1- {Al-Qāri‘ah 1}: Asiko ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ.
🎧 2- {Mal qāri‘ah 2}: Ki ni n jẹ asiko yii ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ?
🎧 3- {Wa mā adrāka mal qāri‘ah 3}: Ki lo mu ọ mọ - irẹ Ojiṣẹ - nkan ti n jẹ asiko yii ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ? Dajudaju oun ni ọjọ igbedide.
🎧 4- {Yaoma yakūnun nāsu kal farāshil mabthūth 4}: Ọjọ ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan, wọn o waa da gẹ́gẹ́ bí afopina ti wọn fọnka síhìn-ín sọ́hùn-ún.
🎧 5- {Wa takūnul jibālu kal ‘ihnil manfūsh 5}: Ati pe awọn oke o wa da gẹgẹ bii òwú ti wọn fi kùmọ̀ lù ki o le lẹ̀, látara yíyára rẹ.
🎧 6- {Fa ammā man thaqulat mawāzīnuhu 6}: Amọ ẹni tí awọn iṣẹ rere rẹ ba tẹsunwọn ju awọn iṣẹ aburu rẹ lọ.
🎧 7- {Fa huwa fī ‘īshatin rādiyah 7}: Nitori naa oun o maa bẹ ninu isẹmi kan ti yio yọ ọ ninu ti yio maa ri i ninu aljanna.
🎧 8- {Wa ammā man khaffat mawāzīnuhu 8}: Amọ ẹniti awọn iṣẹ aburu rẹ ba tẹsunwọn ju awọn iṣẹ rere rẹ lọ.
🎧 9- {Fa ummuhu hāwiyah 9}: Ibugbe rẹ ati ibudo rẹ ni ọjọ Igbedide ni Jahannama.
🎧 10- {Wa mā adrāka mā hiyah 10}: Ki ni o mu ọ mọ - irẹ Ojiṣẹ - nkan naa?!
🎧 11- {Nārun hāmiyah 11}: Oun ni ina kan ti igbona rẹ le gidi.

Ibeere 5: Ka Sūratut Takāthur ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratut Takāthur ati itumọ rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
{’Alhākumut takāthur 1" "Hattā zurtumul maqābir 2" "Kallā saofa ta‘lamūn 3" "Thumma Kallā saofa ta‘lamūn 4" "Kallā lao ta‘lamūna ‘ilmal yaqīn 5" "La tarawunnal jahīm 6" "Thumma la tarawunnahā ‘aynal yaqīn 7" " Thumma la tus’alunna yaoma’idhi ‘anin na‘īm 8} "[Sūratut Takāthur: 1 - 8]"
Alaye:
🎧 1- {’Alhākumut takāthur 1}: Imaa ṣe iyanran pẹlu awọn dukia ati awọn ọmọ ti ko airoju ba yin - ẹyin eniyan - kuro nibi itẹle Ọlọhun.
🎧 2- {Hattā zurtumul maqābir 2}: Titi ti ẹ fi ku ti ẹ si wọ inu awọn sàréè yin.
🎧 3- {Kallā saofa ta‘lamūn 3}: Ko yẹ fun yin ki iṣe iyanran yin pẹlu rẹ (awọn dukia ati ọmọ) o ko airoju ba yin kuro nibi itẹle Ọlọhun, ẹ maa pada mọ atunbọtan ikoairoju yẹn.
🎧 4- {Thumma Kallā saofa ta‘lamūn 4}: Lẹyin naa ẹ maa mọ atunbọtan rẹ.
🎧 5- {Kallā lao ta‘lamūna ‘ilmal yaqīn 5}: Ododo ni ka ni pe ẹ mọ ni amọdaju wipe wọn yio gbe yin dide si ọdọ Ọlọhun, ati pe Yio san yin ni ẹsan awọn iṣẹ yin, ẹ ko nii ko airoju pẹlu imaa ṣe iyanran pẹlu awọn dukia ati awọn ọmọ yin.
🎧 6- {La tarawunnal jahīm 6}: Mo fi Ọlọhun bura ẹ maa ri ina ni ọjọ Igbedide.
🎧 7- {Thumma la tarawunnahā ‘aynal yaqīn 7}: Lẹyin naa ẹ maa ri i ni riri ti o daju ti ko si iyemeji nibẹ.
🎧 8- {Thumma la tus’alunna yaoma’idhin ‘anin na‘īm 8}: Lẹyin naa Ọlọhun o maa bi yin leere ni ọjọ yẹn nipa nkan ti o fi ṣe idẹra le yin lori ninu alaafia ati ọrọ ati nkan miran yatọ si mejeeji.

Ibeere 6: Ka Sūratul Asri ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Asri ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
{Wal Asri 1 " "Innal insāna lafī khusri 2" "Illāl Ladhīna ’āmanū wa ‘amilus sālihāti wa tawāsao bil haqqi watawāsao bis sobr 3}" [Suuratul-Asr: 1-3].
Alaye:

🎧 1- {Wal Asri 1}: Ọba ti mimọ n bẹ fun bura pẹlu igba.
🎧 2- {Innal insāna lafī khusri 2}: itumọ rẹ ni pe: Gbogbo eeyan n bẹ ninu adinku ati iparun.
🎧 3- {Illāl Ladhīna ’āmanū wa ‘amilus soolihaat wa tawāṣao bil haqqi watawāṣao biṣ ṣobr 3}: Ayaafi ẹniti o ba ni igbagbọ ti o si tun ṣe iṣẹ rere, pẹlu iyẹn wọn tun pepe lọ si idi ododo ti wọn si tun ṣe suuru lori rẹ, nitori naa awọn wọnyii ni wọn ti la kuro ninu ofo.

Ibeere 7: Ka Sūratul Humazah ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Humazah ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Wailul-likulli humazatil-lumazah 1 " "Allazee jama’a maalan wa ‘addadah 2 " "Yahsabu anna maalahuu akhladah 3 " "Kallaa; layumbazanna fil hutamah 4 " "Wa maa adrọọka mal-hutọma 5 " "Naarul Lọọhil mu'kọdah 6 " "Allatii tattọlihu ‘alal af’hidah 7 " "Innahaa ‘alaihim muh’sọdah 8 " "Fii ‘amadim mumaddadah 9} " [Surah Al-Humazah 1 - 9]. "
"Alaye:
"
🎧 "1- {Wailul-likulli humazatil-lumazah 1}: Àtúbọ̀tán to buru ati iya to le koko n bẹ fun ẹni ti o pọ ni ọrọ-ẹyin fun àwọn eeyan ati biba wọn jẹ. "
🎧 "2- {Allazee jama’a maalan wa ‘addadah 2}: Ẹni ti o jẹ pe ironu rẹ ni kiko owo jọ ati kika a, ko si ironu miiran fun un yatọ si iyẹn. "
🎧 3- {Yahsabu anna maalahooo akhladah 3}: Ti o n ro pe dajudaju owo rẹ eyi to jẹ pe o kojọ pe yio la a kuro nibi iku, ti yo wa maa ṣe gbere ni isẹmi aye. "
🎧 "4- {Kallaa; layumbazanna fil hutamah 4}: Ọ̀rọ̀ kii ṣe bi alaimọkan yii ṣe ro, dajudaju wọn maa ju u sinu ina jahannamọ eyi ti o maa n run gbogbo nnkan ti wọn ba ju síbẹ̀ nitori ilekoko agbara to n bẹ fun un. "
🎧 "5- {Wa maa adraaka mal-hutamah 5}: Ki ni o mu ọ mọ̀ -iwọ Ojiṣẹ- ki ni ina yii to jẹ pe o maa n run gbogbo nnkan ti wọn ba ju síbẹ̀?! "
🎧 "6- {Naarul laahil-mooqada 6}: Dajudaju oun ni ina Ọlọhun ti o n jò geregere"
🎧 "7- {Allatee tattali’u ‘alal af’idah 7}: Èyí to jẹ pe o maa n ti inú ara àwọn èèyàn bọ sinu awọn ọkan wọn. "
🎧 "8- {Innahaa ‘alaihim mu’sada 8}: Dajudaju wọn maa ti i mọ awọn ti a n fi iya jẹ. "
🎧 "9- {Fee ‘amadin mumaddadah 9}: Pẹ̀lú àwọn òpó kìrìbìtì ti wọn gùn ti wọn ko fi nii le jáde kúrò nibẹ.

"Ibeere kẹjọ: Ka Suuratul Fiil, ki o si ṣe alaye ẹ? "

"Idahun- Suuratul Fiil ati alaye ẹ: "
"Bismillah hir Rahman nir Raheem "
"{Alam tara kaifa fa’ala rabbuka bi as’haabil feel 1 " "Alam yaj’al kaidahum fee tadleel 2 " "Wa arsala ‘alayhim tayran ’abābīl 3" "Tarmīhim bi hijāratim min sijjīl 4" " Fa ja‘alahum ka ‘asfin ma’kūl 5} * [Sūratul Fīl: 1 - 5].
Alaye
🎧 1- {Alam tarọ kayfa fa‘ala Rọbbuka bi as’haabil fīl 1}: Ṣe o o wa mọ - irẹ ojiṣẹ- bi Oluwa rẹ ṣe ṣe Abrahatu ati awọn eeyan rẹ awọn eleerin nigba ti won fẹ wo ka‘bah?!
🎧 2- {Alam yaj‘al kaydahum fī tadlīl 2}: Ọlọhun ti sọ ìpètepèrò aburu wọn lati wo o di anu, ọwọ wọn ko si tun tẹ nkan ti wọn fẹ lati siju awọn eeyan kuro ni ka‘bah, ọwọ wọn ko si tẹ nkankan ninu rẹ.
🎧 3- {Wa arsala ‘alayhim tayran ’abābīl 3}: O si tun gbe awọn ẹyẹ kan dide si wọn ti wọn wa ba wọn nijọnijọ.
🎧 4- {Tarmīhim bi hijāratin min sijjīl 4}: Ti wọn n ju wọn ni oko lati ara amọ̀ ti o le bii òkúta.
🎧 5- {Fa ja‘alahum ka ‘asfin ma’kūl 5}: Ọlọhun wa ṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ewe irugbin ti awọn ẹranko ti jẹ ẹ ti o si tun ti tẹ ẹ mọlẹ.

Ibeere 9: Ka Sūratu Quraysh ki o si ṣe alaye rẹ?.

Idahun- Sūratu Quraysh ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Li ’īlāfi Quraysh 1 " "’Īlāfihim rihlatash shitā’i was sayf 2" " Fal ya‘budū robba hādhal bayt 3" "Allādhī ’at‘amahum min jū‘in wa āmanahum min khaof 4} [Sūratu Quraysh 1 - 4].
Alaye:

🎧 1- {Li ’īlāfi Quraysh 1}: Itumọ iyẹn ni nkan ti wọn ti ba saaba ni ṣiṣe irin-ajo ni asiko ọyẹ ati ni asiko ooru.
🎧 2- {’Īlāfihim rihlatash shitā’i was sayf 2}: Irin-ajo asiko ọyẹ lọ sí ilu Yemen, ati irin-ajo asiko ooru lọ sí ilu Shām lẹniti ọkan wọn balẹ.
🎧 3- {Fal ya‘budū robba hādhal bayt 3}: Ki wọn yaa maa sin Allāhu Oluwa ile abọwọ yii ni Oun nikan ṣoṣo, Ẹnití O ṣe irin-ajo yii ni irọrun fun wọn, ti wọn o si gbọdọ mu nkankan mọ Ọn ni orogun.
🎧 4- {Allādhī ’at‘amahum min jū‘in wa āmanahum min khaof 4}: Ẹniti maa n fun wọn ni jijẹ ninu ẹbi, ti si maa n fi ọkan wọn balẹ ninu ipaya, pẹlu nkan ti O fi si awọn ọkan awọn larubawa ni imaa gbe ile abọwọ naa tobi, ati imaa gbe awọn olugbe ibẹ tobi.

Ibeere 10: Ka Sūratul Mā‘ūn ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Mā‘ūn ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1" "Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2" "Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3" "Fa waylun lil musọlliin 4" "Allādhīna hum ‘an sọlaatihim sāhūn 5" "Alladhīna hum yurā’ūn 6" "Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}" "[Sūratul Mā‘ūn: 1 - 7].
Alaye:

🎧 1- {Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1}: Njẹ o mọ ẹni tí maa n pe ẹsan ti ọjọ Igbedide ni irọ.
🎧 2- {Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2}: Oun ni ẹni naa ti maa n fi agbara le ọmọ orukan danu kuro nibi gbigbọ bukaata rẹ.
🎧 3- {Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3}: Ko si ki n ṣe ẹmi rẹ ni ojukokoro, ko si tun ki n ṣe ẹlomiran ni ojukokoro lori fifun alaini ni ounjẹ.
🎧 4- {Fa waylun lil musalliin 4}: Nitori naa iparun ati iya ko maa bẹ fun awọn kirunkirun.
🎧 5- {Allādhīna hum ‘an salaatihim sāhūn 5}: Awọn ti wọn maa n gbagbera kuro nibi Irun wọn, ti wọn o si ki n bikita pẹlu rẹ titi ti asiko rẹ o fi lọ.
🎧 6- {Alladhīna hum yurā’ūn 6}: Awọn ti wọn maa n ṣe ṣekarimi pẹlu Irun wọn ati awọn iṣẹ wọn, wọn o si ki n mọ iṣẹ kanga fun Ọlọhun.
🎧 7- {Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}: Wọn o si maa kọ lati ṣe iranlọwọ fun ẹni tí o yatọ si wọn pẹlu nkan ti ko si inira kankan nibi ṣiṣe iranlọwọ pẹlu rẹ.

Ibeere 11: Ka Sūratul Kaothar ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Kaothar ati alaye rẹ:
" BismiLlāhir Rahmānir Rahīm "
{Innā a‘taynākal kaothar 1 " " Fa salli li robbika wanhar 2 " " Inna shāni’aka huwal ’abtar 3} " [Suuratul-Kawthar: 1-3].
Alaye
🎧 1- {Innā a‘taynākal kaothar 1}: Dajudaju Awa ni A fun ọ - irẹ Ojiṣẹ - ni oore ti o pọ, ninu rẹ naa si ni abata Kaothar ninu al-Jannah.
🎧 2- {Fa salli li robbika wanhar 2}: Nitori naa dúpẹ́ fun Ọlọhun rẹ lori idẹra yii, pẹlu ki o kirun fun Un ki o si pa ẹran fun Un ni Oun nikan ṣoṣo, yatọ si nkan ti awọn ọṣẹbọ maa n ṣe nibi imaa wa asunmọ awọn oriṣa wọn pẹlu pipa nkan fun wọn.
🎧 3- {Inna shāni’aka huwal ’abtar 3}: Dajudaju ẹniti ba n binu rẹ (korira rẹ) oun ni ẹniti o ja kuro nibi gbogbo daadaa, ẹni igbagbe ti o ṣe wipe ti wọn ba ranti rẹ wọn o ranti rẹ pẹlu aburu ni.

Ibeere 12: Ka Sūratul Kāfirūn ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Kāfirūn ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Qul yā ayyuhal kāfirūn 1" "Lā a‘budu mā ta‘budūn 2" "Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 3" "Walā anā ‘ābidun mā ‘abadtum 4" "Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 5" "Lakum dīnukum waliya dīni 6}" [Suuratul-Kafirun: 1-6].
Alaye
🎧 1- {Qul yā ayyuhal kāfirūn 1}: Sọ - irẹ Ojiṣẹ - pe mo pe ẹyin ti ẹ ṣe aigbagbọ pẹlu Ọlọhun.
🎧 2- {Lā a‘budu mā ta‘budūn 2}: Mi o nii sin nkan ti ẹ n sin ni awọn oriṣa lọwọlọwọ báyìí ati ni ọjọ iwaju.
🎧 3- {Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 3}: Ati pe ẹyin o nii sin nkan ti emi n sin, Oun naa ni Allāhu ni Oun nikan ṣoṣo.
🎧 4- {Walā anā ‘ābidun mā ‘abadtum 4}: Ati pe emi o nii sin nkan ti ẹ n sin ni awọn oriṣa.
🎧 5- {Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 5}: Ati pe ẹyin o nii sin nkan ti emi n sin, Oun naa ni Allāhu ni Oun nikan ṣoṣo.
🎧 6- {Lakum dīnukum waliya dīni 6}: Ti yin ni ẹsin yin ti ẹ da silẹ funra yin, temi naa si ni ẹsin mi ti Ọlọhun sọkalẹ fun mi.

Ibeere 13: Ka Sūratun Nasr ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratun Nasr ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Idhā jā’a nasrul Lāhi wal fath 1" "Wa ra’aytan nāsa yadkhulūna fī dīnil Lāhi afwājā 2" "Fa sabbih bi hamdi rabbika wastagfirhu innahu kāna tawwābā 3}" "[Sūratun Nasri: 1 - 3]"
Alaye:
🎧 3- {Idhā jā’a nasrul Lāhi wal fath 1}: Ti aranse Ọlọhun ba ti de fun ẹsin rẹ - irẹ Ojiṣẹ -, ati fífún un ní agbára, ti ṣiṣi Mẹka si ṣẹlẹ.
🎧 2- {Wa ra’aytan nāsa yadkhulūna fī dīnil Lāhi afwājā 2}: Wàá ri awọn eeyan ti wọn o maa wọ inu Isilaamu ni ikọ kan lẹyin ikọ miran.
🎧 3- {Fa sabbih bi hamdi rabbika wastagfirhu innahu kāna tawwābā 3}: Lọ mọ wipe dajudaju iyẹn ami ipari iṣẹ ti wọn tori rẹ gbe ọ dide ni, nitori naa ṣe afọmọ pẹlu fifi ẹyin fun Oluwa rẹ, ki o fi wa aforijin lọdọ rẹ, dajudaju Oun ni Olugba-tuuba ti maa n gba tuuba awọn ẹrusin Rẹ, ti si tun maa n ṣe aforijin fun wọn.

Ibeere 14: Ka Sūratul Masad ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Masad ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
{Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1" "Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2" "Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3" "Wamra’atuhu hammālatal hatab 4" "Fī jīdihā hablun min masad 5} "[Sūratul Masad: 1 - 5]"
Alaye
🎧 1- {Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1}: Ọwọ mejeeji ọmọ-ìyá baba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tii ṣe Abu Lahabi ọmọ Abdul Muttalib ti p'ofo latari ipofo iṣẹ rẹ, nitori pe o maa n fi suta kan Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nitori naa wahala rẹ ja si ofo.
🎧 2- {Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2}: Ki ni nkan ti dukia ati ọmọ rẹ fi ṣe e ni anfaani? Wọn o lee ti iya danu fun un, bẹẹ si ni wọn o lee fa ikẹ wa fun un.
🎧 3- {Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3}: Yio si wọ ina eléjò fòfò, ti yoo maa fojú winá ooru rẹ.
🎧 4- {Wamra’atuhu hammālatal hatab 4}: Iyawo rẹ Ummu Jamīl naa o wọ ọ (ina), ẹniti o ṣe wipe o maa n ni Anabi lara pẹlu dida ẹgun si oju-ọna rẹ.
🎧 5- {Fī jīdihā hablun min masad 5}: Okun kan ti wọn lọ yanjú (daadaa) wa ni orun rẹ ti wọn o fi wọ ọ lọ si inu ina.

Ibeere 15: Ka Sūratul Ikhlās ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Ikhlās ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Qul Uwa Allāhu Ahad 1" "Allāhus Sọmad 2" "Lam yalid wa lam yūlad 3" "Wa lam yakun lahu kufwan ahad}" "[Sūratul Ikhlās: 1 - 4]"
Alaye
🎧 1- {Qul Uwa Allāhu Ahad 1}: Sọ - irẹ Ojiṣẹ -: Oun ni Ẹniti ijọsin tọ si, ko si ẹlomiran ti ijọsin tọ si yatọ si I.
🎧 2- {Allāhus Sọmad 2}: Itumọ rẹ ni pe: Ọdọ Rẹ ni wọn maa n gbe awọn bukaata awọn ẹda lọ.
🎧 3- {Lam yalid wa lam yūlad}: Ko si ọmọ fun Un ko si si baba (mimọ n bẹ fun Un).
🎧 4- {Wa lam yakun lahu kufwan ahad 4}: Ko si ẹniti o jọ ọ ninu awọn ẹda Rẹ.

Ibeere 16: Ka Sūratul Falaq, ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Falaq ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Qul a‘ūdhu bi robbil falaq 1" "Min sharri mā khalaqa 2" "Wa min sharri gāsiqin idhā waqaba 3" "Wa min sharrin naffāthāti fil ‘uqad 4" "Wa min sharri hāsidin idhā hasada 5}" "[Sūratul Falaq: 1 - 5]"
Alaye
🎧 1- {Qul a‘ūdhu bi robbil falaqi 1}: Sọ pe - irẹ Ojiṣẹ - mọ wa iṣọra pẹlu Ọba owurọ, mo si wa ààbò pẹlu Rẹ.
🎧 2- {Min sharri mā khalaqa 2}: Nibi aburu nkan ti maa n fi suta kan eeyan ninu awọn ẹda Rẹ.
🎧 3- {Wa min sharri gāsiqin idhā waqaba 3}: Mo si tun wa isadi pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn aburu ti maa n han ni oru lati ọwọ awọn ẹranko ati awọn ole.
🎧 4- {Wa min sharrin naffāthāti fil ‘uqad 4}: Mo si tun dirọ mọ Ọn kuro nibi aburu àwọn opindan lóbìnrin ti wọn maa n fẹ atẹgun tuẹtuẹ si inu awọn koko.
🎧 5- {Wa min sharri hāsidin idhā hasada 5}: Ati kuro nibi aburu oni keeta ti maa n binu wọn, nígbà tí o ba ṣe keeta wọn nibi nkan ti Ọlọhun fi ta wọn lọrẹ ninu idẹra, ti o n fẹ ki o yẹ kuro lọdọ wọn, ati ki aburu o ṣẹlẹ si wọn.

Ibeere 17: Ka Sūratun Nās ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratun Nās ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
"{Qul a‘ūdhu bi robbin nās 1" "Malikin nās 2" "Ilāhin nās 3" "Min sharril waswāsil khannās 4" "Alladhī yuwaswisu fī suduurin nās 5" "Minal jinnati wan nās 6}" "[Sūratun Nās: 1 - 6]"
Alaye
🎧 1- {Qul a‘ūdhu bi robbin nās 1}: Sọ- irẹ ojiṣẹ - pe: Mo wa isadi pẹlu Ọba awọn ènìyàn, mo si tun wa aabo pẹlu Rẹ̀.
🎧 2- {Malikin nās 2}: O maa n ṣe nkan ti o ba wu u si wọn, ko si olukapa miran fun wọn yatọ si I.
🎧 3- {Ilāhin nās 3}: Ẹni tí wọn o maa jọsin fun lododo ni I, ti ko si si ẹni ti ìjọsìn tọ si fun wọn yàtọ̀ si I.
🎧 4- {Min sharril waswāsil khannās 4}: Kuro nibi aburu shaytān ti o maa n ju royiroyi rẹ si awọn eeyan.
🎧 5- {Alladhī yuwaswisu fī suduurin nās 5}: O maa n ju royiroyi rẹ si ọkan awọn ọmọniyan.
🎧 6- {Minal jinnati wan nās 6}: Ìtumọ̀ rẹ ni pé: Ẹniti maa n ko royiroyi báni le jẹ ninu awọn eeyan, o si le jẹ ninu awọn alujannu.

Ipin Hadīth14

Ibeere 1: Parí hadīth: «Innamal a‘mālu bin niyyaat...», ki o si tun sọ díẹ̀ nínú awọn anfaani rẹ?

Idahun- Lati ọdọ alaṣẹ awọn olugbagbọ ododo tii ṣe baba Hafs, Umar ọmọ khatāb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Dajudaju gbogbo iṣẹ n bẹ pẹlu aniyan, ati pe gbogbo nkan ti ọmọniyan kọọkan ba gbero ni yio maa jẹ tiẹ, nitori naa ẹniti o ba ṣe hijirah tiẹ̀ nítorí ti Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ; yio gba ẹsan hijira rẹ nitori ti Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ, ẹniti o ba si ṣe hijirah tiẹ̀ nitori aye tabi nitori obinrin ti o fẹẹ fẹ; ẹsan hijirah rẹ o maa bẹ lori nkan ti o tori rẹ ṣe hijirah». Bukhārī ati Muslim ni wọn gba a wa.
Awọn anfaani inu Hadīth:

1- Ko si ibuyẹ fun gbogbo iṣẹ nibi aniyan, bii Irun, ati Aawẹ, ati Hajj, ati eyiti o yatọ si i ninu awọn iṣẹ.
"2- Èèyàn gbọdọ̀ ni imọkanga nibi aniyan fun Ọlọhun."
"Hadīth ẹlẹẹkeji:
"

"Ibeere 2: Pari hadīth «Man ’ahdatha fī amrinā hādhā ...», ki o si tun darukọ awọn anfaani rẹ?"

"Idahun- Lati ọdọ iya gbogbo Mu’mini Umu Abdullāhi ‘Āishah ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:" "«Ẹniti o ba da adadaalẹ ni inu alamọri yii ti ko si ninu rẹ, yio jẹ adapada fun un»" Bukhaari ati Muslim ni wọn gba a wa
"Awọn anfaani lati inu Hadīth yii:"
"1- kikọ kuro nibi adadaalẹ ninu ẹsin"
"2- Ati pe dajudaju gbogbo iṣẹ ti o jẹ adadaalẹ nkan ti wọn o da pada ni ti ko nii jẹ atewọgba"
"Hadīth ẹlẹẹkẹta:
"

Ibeere 3: Parí hadiisi (baenamaa nahnu juluusun inda rọsuulullaahi- solla Loohu alaehi wa sallam-) ki o si sọ díẹ̀ nínú àwọn anfaani rẹ.

"Idahun- Lati ọdọ Umar ọmọ Khataab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Láàrin ìgbátí a jókòó si ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ọjọ kan, arakunrin kan yọ si wa ti asọ rẹ funfun gbòò, irun ori rẹ si dudu kirikiri, a o si ri apẹrẹ arìnrìn-àjò lara rẹ, ẹnikankan o si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa fi orunkun rẹ mejeeji ti orunkun rẹ (Anabi), o si tun gbe ọwọ rẹ mejeeji le ori itan rẹ mejeeji, o wa sọ pe: «Irẹ Muhammad, fun mi ni iro nipa Isilaamu», o wa sọ fun un pe: «Nkan ti n jẹ Isilaamu ni: ki o jẹrii wipe ko si ẹniti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad Ojiṣẹ Rẹ ni, ki o si maa gbe Irun duro, ki o si tun maa yọ Zakah, ki o tun maa gba Aawẹ Ramadan, ki o si tun lọ si Ile Ọlọhun ti o ba kapa ọna atilọ», o sọ pe: «ododo ni o sọ», o waa ya wa lẹnu fun un pe oun ni n bi i leere oun naa ni o tun n fi ododo rẹ rinlẹ, o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa ’Īmān (Igbagbọ)», o sọ pe: «ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹhin, ki o si tun ni igbagbọ ninu kadara, daadaa rẹ ni abi aburu rẹ», o sọ pe: «ododo ni o sọ», o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa ’Ihsān», o sọ pe: «ki o maa sin Ọlọhun bi wipe o n ri I, ti o o ba ri I, dajudaju Oun n ri ọ», o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa As Sā‘ah (Igbẹyin aye)», o sọ pe: «ki ẹrubinrin o maa bi olowo rẹ, ki o si tun maa ri awọn ti wọn ko nii wọ bàtà, ati awọn arinhoho, ati awọn alaini awọn adaranjẹ, ti wọn a maa kọ awọn ile giga ni ti ìdíje» lẹyin naa ni o wa lọ, mo wa ṣe suuru fun igba diẹ, lẹyin naa, o wa sọ pé: «Irẹ Umar, njẹ o mọ onibeere yẹn?», mo sọ pe: "Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ nikan ni wọn ni imọ julọ", o sọ pe: «Jibrīlu ni, o wa ba yin lati fi ẹsin yin mọ yin»" Muslim ni o gba a wa.
"Ninu awọn anfaani inu Hadīth yii:
"
1- Didarukọ awọn origun Isilaamu maraarun, awọn naa ni:
"Ijẹrii pe ko si ẹniti ijọsin tọ si l'ododo ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni"
"Ati gbigbe Irun duro"
"Ati yiyọ Zakah"
"Ati gbigba aawẹ Ramadan"
"Ati ṣíṣe hajj lọ si ile Ọlọhun abeewọ"
2- Didarukọ awọn origun igbagbọ, mẹfa ni:
"Nini igbagbọ ninu Ọlọhun"
"Ati awọn malaika Rẹ"
"Ati awọn tira Rẹ"
"Ati awọn ojiṣẹ Rẹ"
Ati ọjọ ikẹyin."
Ati kadara, eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru nibẹ."
"3- Didarukọ origun ṣíṣe dáadáa, origun kan ni, oun ni ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba ri I, dajudaju Oun n ri ẹ."
"4- Asiko ọjọ igbedide, ko si ẹni kan kan ti o ni imọ nipa ẹ afi Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-. "
"Hadisi ẹlẹẹkẹrin:
"

"Ibeere ẹlẹẹkẹrin: Parí hadisi “ẹni ti o pe ju ni ìgbàgbọ́ nínú àwọn mumini…”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ?"

"Idahun- lati ọdọ Abu Hurayra -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ẹni ti o pe julọ ninu awọn mumini ni igbagbọ: Ni ẹni ti o dára julọ ninu wọn ni iwa”. "Tirmidhi ni o gba a wa, o wa sọ pe: “Hadiisi to daa ni to ni alaafia".
"Awọn anfaani to wa ninu hadiisi naa”

"1- Iṣenilojukokoro si iwa dáadáa. "
"2- Dajudaju pipe iwa wa ninu pipe igbagbọ. "
3- Igbagbọ a maa lekun a si maa dikun. "
"Hadisi karun-un: "

"Ibeere ẹlẹẹkarun-un: Parí hadiisi: “Ẹni ti o ba bura pẹlu nnkan to yatọ si Ọlọhun....”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ?"

"Idahun- lati ọdọ Ibn Umar -ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ẹni ti o ba bura pẹlu nnkan to yatọ si Ọlọhun; ti ṣe aigbagbọ tabi da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun”." Tirmidhiy ni o gba a wa
"Awọn anfaani to wa ninu hadiisi naa:
"
"1- Bibura ko tọ afi pẹlu Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
"2- Bibura pẹlu nnkan to yatọ si Ọlọhun wa ninu ẹbọ kekere."
"Hadiisi kẹfa:
"

"Ibeere ẹlẹẹkẹfa: Parí Hadiisi: “Ẹnikẹ́ni ninu yin o ni tii di olugbagbọ titi maa fi di ẹni ti o ni ifẹ si julọ....” ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ? "

"Idahun- lati ọdọ Anas -ki Ọlọhun yọnu si i-, Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ẹnikẹni ninu yin o ni tii di olugbagbọ titi maa fi di ẹni ti o ni ifẹ si ju obi rẹ lọ, ati ọmọ rẹ, ati gbogbo eniyan patapata”. "Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. "
"Ninu awọn anfaani to wa ninu Hadiisi naa:
"
Nini ifẹ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju gbogbo eniyan lọ jẹ dandan. "
Ati pe iyẹn wa ninu pipe igbagbọ.
Hadiith eleekeje.

"Ibeere ẹlẹẹkeje: Parí hadisi: “Ẹni kan kan ninu yin o ni tii di olugbagbọ titi yoo fi fẹ fun ọmọ iya rẹ…”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani rẹ? "

"Idahun- lati ọdọ Anas -ki Ọlọhun yọnu si i-, Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ẹni kan kan ninu yin o ni tii di olugbagbọ titi yoo fi fẹ fun ọmọ iya rẹ nnkan to fẹ fun ara rẹ”. " "Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. "
"Ninu awọn anfaani to wa ninu Hadiisi naa:
"
"1- O jẹ dandan fun olugbagbọ lati fẹ fun awọn olugbagbọ ninu dáadáa gẹgẹ bi o ṣe fẹ fun ara rẹ. "
Ati pe iyẹn wa ninu pipe igbagbọ.
"Hadiisi kẹjọ:
"

"Ibeere ẹlẹẹkẹjọ: Parí Hadiisi: “Mo fi Ẹni ti ẹmi mi wa lọwọ Rẹ bura…!, ki o si darukọ diẹ nínú awọn anfaani ẹ? "

"Idahun- lati ọdọ Abu Saheed -ki Ọlọhun yọnu si i- Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Mo fi Ẹni ti ẹmi mi wa lọwọ Rẹ bura! dajudaju o ṣe déédéé idamẹta Kuraani”. "Bukhari ni o gba a wa. "
Anfaani ti a maa ṣe lara Hadiisi naa ni pe
1- Ọla to n bẹ fun Surah Al-Ikhlaas. "
2- Ati pe o ṣe déédéé idamẹta Kuraani.
"Hadiisi kẹsan-an: "

"Ibeere ẹlẹẹkẹsan-an: Parí Hadiisi: “Laa hawla wa laa quwwata illa bi-Llah…”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ? "

"Idahun- lati ọdọ Abu Musa -ki Ọlọhun yọnu si i- Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Laa hawla wa laa quwwata illa bi-Llah jẹ pẹpẹ ọrọ kan ninu awọn pẹpẹ ọrọ alujanna”. Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa.
Ninu awọn anfaani Hadiisi yii:

1- Ọla ti n bẹ fun gbolohun yii, ati pe pẹpẹ ọrọ kan ni in ninu awọn pẹpẹ ọrọ alijanna.
2- Yoo mu ẹrusin bọpa bọsẹ kuro nibi ìkápá ati agbara rẹ ati gbigbara le Ọlọhun (Ọba ti O ga) nikan ṣoṣo.
Hadiisi kẹwàá:

Ibeere 10: Pari hadiisi “Ẹ gbọ o, baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara…”, ki o si darukọ awọn apa kan anfaani rẹ?

Idahun: Nu'maan ọmọ Basheer (ki Ọlọhun yọnu si i) sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) n sọ pe: “Ẹ gbọ o, baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara, ti o ba dara, gbogbo ara ni yoo dara, ti o ba si bajẹ, gbogbo ara ni yoo bajẹ, ẹ gbọ o, oun naa ni ọkan”. "Bukhaari ati Muslim ni wọn gba a wa."
Awọn apa kan anfaani hadiisi yii:

1- Didara ọkan yoo jẹ ki gbangba ati kọkọ o dara.
2 – Nini akolekan didara ọkan, nitori pe ibẹ ni didara ọmọniyan wa.
Hadiisi ẹlẹẹkọkanla:

Ibeere 11: Parí hadiisi yii: “Ẹni ti igbẹyin ọrọ rẹ nile aye ba jẹ: Laa ilaaha ilaLlah...”, ki o si darukọ awọn apa kan anfaani rẹ?

Idahun: Lati ọdọ Muaadh ọmọ Jabal (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: “Ẹni tí igbẹyin ọrọ rẹ nile aye ba jẹ: Laa ilaaha illaal Looh; yoo wọ alijanna”. Abu Daud ni o gba a wa.
Diẹ ninu awọn anfaani hadiisi naa:

1- Ọla ti n bẹ fun "Laa ilaaha illaLlaah" ati pe ẹrusin yoo wọ alujanna pẹlu rẹ.
2- Ọla ti n bẹ fun ẹni tí igbẹyin ọrọ rẹ ni ile aye yii ba jẹ "Laa ilaaha illaLlaah"
Hadiisi ẹlẹẹkejila:

Ibeere 12: Pari Hadiisi “Kii ṣe olugbagbọ ododo ni ẹni tí maa n saaba bu ẹnu atẹ lu àwọn èèyàn, tabi ẹni ti máa n saaba sẹbi le àwọn eeyan…”, ati diẹ ninu awọn anfaani rẹ?

Idahun: Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'uud (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: "Mu'mini o ki n ṣe ẹni tí maa n yọ aleebu ara eeyan, ko si ki n ṣe ẹni tí maa n ṣepe, ko si ki n ṣe oni ibajẹ, ko si ki n ṣe ẹlẹnu jijo (ti ko si ọrọ ti ko le sọ) Tirmidhiy ni o gba a wa
Ninu awọn anfaani Hadiisi yii:
"1-Kikọ kuro nibi gbogbo ọrọ ibajẹ ati ọrọ buruku. "
Dajudaju iyẹn jẹ iroyin olugbagbọ nibi ahọn rẹ. "
Hadiisi kẹtala:
"

"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Parí hadiisi: “Ninu didara Isilaamu ọmọniyan...”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ?"

Idahun- lati ọdọ Abu Hurayra -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ninu dida Isilaamu ọmọniyan: Ni ki o maa gbe nnkan ti ko ba kan an ju silẹ”. "Tirmidhi ati ẹni ti o yatọ si i ni wọn gba a wa.
"Ninu awọn anfaani to wa ninu hadiisi naa:
"
"1- Gbigbe nnkan ti ko ba kan eniyan ju silẹ ninu awọn alamọri ẹsin ẹlomiran ati aye rẹ. "
"2- Ki o gbe nnkan ti ko kan an ju silẹ wa ninu pipe ẹsin rẹ. "
"* Hadiisi kẹrinla:
"

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinla: Parí hadiisi: “Ẹni ti o ba ka arafi kan ninu iwe Ọlọhun…”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ? "

"Idahun- lati ọdọ Abdulahi ọmọ Mas'ud: Pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ẹni ti o ba ka arafi kan ninu iwe Ọlọhun yio gba dáadáa kan pẹlu ẹ, ati pe dáadáa jẹ ilọpo mẹ́wàá iru ẹ, mi ko sọ pe: Alif Lam Mim jẹ arafi kan, bi ko ṣe pe Alif jẹ arafi kan, Lam jẹ arafi kan, Mim jẹ arafi kan”. Tirmidhiy ni o gba a wa
"Ninu awọn anfaani to wa ninu hadiisi naa:

"1- Ọla ti n bẹ fun kika Kuraani."
2- Dáadáa o maa wa fun ẹ fun gbogbo arafi kọọkan ti o n ka. "

"Abala awọn ẹkọ ti Isilaamu"26

"Ibeere kini- bawo ni ẹkọ pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ṣe maa jẹ? "

"Idahun- 1- gbigbe E tobi -mimọ ni fun Un Ọba ti ọla Rẹ ga- "
"2- Jijọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun kankan fun Un. "
"3- Titẹle E. "
4- Gbigbe yiyapa aṣẹ Rẹ ju silẹ. "
"5- Didupẹ fun Un ati yiyin In, Alagbara ti O gbọnngbọn lori ọla Rẹ ati awọn idẹra Rẹ eleyii ti ko ṣee ka. "
"6- Ati ṣiṣe suuru lori awọn ìpinnu Rẹ. "

"Ibeere keji: Báwo ni ẹkọ pẹlu Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa jẹ? "

"Idahun- 1- Titẹle e ati ikọṣe rẹ. "
"2- Titẹle aṣẹ rẹ. "
"3- Gbigbe yiyapa rẹ ju silẹ. "
"4- Gbigba a lododo nibi nnkan ti o ba sọ. "
"5- Aida adadaalẹ nipa ṣiṣe alekun lori oju-ọna rẹ. "
"6- Nini ifẹ rẹ ju ara ẹni lọ ati ju gbogbo eniyan lọ. "
"7- Gbigbe e tobi ati riran an lọwọ ati riran sunna rẹ lọwọ. "

"Ibeere kẹta: Báwo ni nini ẹkọ pẹlu awọn obi mejeeji ṣe maa jẹ? "

"Idahun- 1- titẹle aṣẹ awọn obi mejeeji nibi nnkan to yatọ si ẹṣẹ. "
"2- Sisin awọn obi mejeeji. "
"3- Ṣíṣe ikunlọwọ fun awọn obi mejeeji. "
"4- Bibiya awọn bukaata awọn obi mejeeji. "
"5- Ṣiṣe adura fun obi mejeeji."
"6- Lílo ẹkọ pẹlu wọn nibi ọrọ; ṣiṣe "ṣiọ" wọn ko tọ, oun ni eyi to kere julọ ninu awọn ọrọ"
"7- Mimaa rẹẹrin-musẹ loju awọn obi mejeeji, mi o si nii lejú. "
"8- Mi o nii gbe ohun mi soke ju ohun awọn obi mejeeji lọ, maa maa gbọ ọrọ si wọn lẹnu, mi o nii da ọrọ mọ wọn lẹnu, mi o nii pe wọn pẹlu orúkọ awọn mejeeji, bi ko ṣe pe maa sọ pe: "Bàbá mi", "iya mi". "
"9- Maa gba iyọnda lọwọ wọn ṣíwájú ki n to wọle ti baba mi ati iya mi ti awọn mejeeji si wa ninu yara. "
"10- Fifi ẹnu ko ọwọ ati ori awọn obi mejeeji. "

"Ibeere kẹrin: Báwo ni maa ṣe so okun-ibi pọ? "

"Idahun-1- Ṣiṣẹ abẹwo awọn mọlẹbi bi ọmọ-iya l'ọkunrin ati ọmọ-iya lobinrin, ati ọmọ-iya baba ẹni l'ọkunrin ati ọmọ-iya baba ẹni lobinrin, ati ọmọ-iya iya ẹni l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya ẹni lobinrin, ati awọn mọlẹbi yoku."
"2- Imaa ṣe daadaa si wọn pẹlu ọrọ ati isẹ ati imaa ran wọn lọwọ."
"3- Ninu rẹ tun ni imaa pe wọn ati imaa beere nipa ìṣesí wọn.'

"Ibeere 5: Bawo ni maa ṣe ri pẹlu awọn ọmọ-iya mi ati awọn ọrẹ mi?"

"Idahun-1- Maa nífẹ̀ẹ́, maa si maa ba awọn ẹnirere ṣe ọrẹ."
"2- Maa jina si biba awọn eeyan buruku ṣe ọ̀rẹ́, maa si gbe e ju silẹ."
"3- Maa salamọ si awọn ọmọ-ìyá mi, maa si bọ wọn lọwọ."
"4- Maa bẹ wọn wo ti wọn ba ṣe aisan, maa si ṣe adua iwosan fun wọn."
"5- Maa ki ẹniti o ba sin."
"6- Maa jẹ ipe rẹ ti o ba pe mi lati bẹ ẹ wo."
"7- Maa gba a ni imọran."
"8- Maa ran an lọwọ ti wọn ba ṣe abosi rẹ, maa si kọ fun un kuro nibi abosi."
"10- Maa nífẹ̀ẹ́ fun ọmọ-ìyá mi ti o jẹ Musulumi nkan ti mo ba n fẹ funra mi."
"11- Maa ran an lọwọ ti o ba bukaata si iranlọwọ mi."
"12- Mio nii fi suta kan an, yala pẹlu ọrọ ni tabi iṣe."
"13- Maa sọ kọkọ rẹ."
"14- Mi o nii bu u, mi o si nii sọ ọrọ rẹ lẹyin, tabi yẹpẹrẹ rẹ, tabi ṣe keeta rẹ, tabi tọpinpin rẹ, tabi ki n rẹ ẹ jẹ."

"Ibeere 6: Ki ni awọn ẹkọ alámùlétì?"

"Idahun- Maa ṣe daadaa si alamuleti pẹlu ọrọ ati iṣe, maa si ran an lọwọ nígbà tí o ba bukaata si iranlọwọ mi."
"2- Maa ki i nígbà tí o ba n yọ ayọ ọdun, tabi igbeyawo tabi èyí tí o yatọ si i."
"3- Maa bẹ ẹ wo ti aisan ba ṣe e, maa si ba a kẹdun ti ajalu ba ṣẹlẹ si i."
"4- Maa gbe eyi ti o ba rọrun ninu ounjẹ ti mo ba se fun un."
"5- Mi o nii fi suta kankan kan an pẹlu ọrọ ni abi iṣe."
"6- Mi o nii da a láàmú pẹlu ohun to lọ soke tabi ki n maa tọpinpin rẹ, ati pe maa ṣe suuru fun un. "

"Ibeere keje: Ki ni awọn ẹkọ iṣe alejo ati alejo? "

"Idahun- 1- maa da ẹni ti o ba pe mi lóhùn fun igbalejo rẹ. "
"2- Ti mo ba fẹ bẹ ẹnikẹni wo, maa gba iyọnda ati àsìkò. "
3- Maa gba iyọnda ki n to wọle. "
"Mi o nii pẹ nibi abẹwo."
"5- Maa rẹ oju nilẹ fun awọn ara ile. "
"6- Maa ki alejo kaabọ, maa si gba àlejò dáadáa pẹ̀lú itujuka, ati eyi to daa julọ ninu awọn agbekalẹ ọrọ ikinikaabọ. "
"7- Maa mu alejo jókòó si ààyè to daa julọ. "
"8- Maa pọn ọn lé pẹlu iṣe alejo pẹ̀lú jijẹ ati mimu. "

"Ibeere kẹjọ: Dárúkọ awọn ẹkọ aisan ati bibẹ awọn alaisan wo? "

"Idahun- 1- Ti mo ba ti n mọ inira lara; maa gbe ọwọ mi ọtun le aaye ẹ, maa sọ pe: “Bismillaah” lẹẹmẹta, maa si sọ pe: “A'uudhu bi izzatillahi wa kudrotihi min sharri maa ajidu wa uhaadhir” lẹẹmeje. "
"2- Maa yọnu si nnkan ti Ọlọhun kadara ẹ, maa si ṣe suuru. "
"3- Maa yara lati lọ bẹ ọmọ-iya mi alaisan wo, maa si ṣe adura fun un, mi o si nii jókòó pẹ lọdọ rẹ. "
"4- Maa ṣe ruk'ya fun un láìní jẹ ki o beere pe ki n ṣe e fun oun. "
"5- Maa sọ asọtẹlẹ fun un pẹlu suuru ati adura, ati irun kiki ati imọra bi o ba ṣe kapa mọ.
"6- Adura fun alaisan: “As’alul Lọọhal Aziim, Rọbbal Ar'shil Aziim, an yash’fiyanii” lẹẹmeje. "

"Ibeere kẹsan-an: Dárúkọ awọn ẹkọ wiwa imọ? "

"Idahun- 1- Mimọ aniyan kanga fun Ọlọhun Alagbara ti O gbọnngbọn.
2- Maa maa ṣe amulo imọ ti mo kọ "
"3- Maa maa ṣe apọnle olukọ ni oju rẹ ati ni ẹyin rẹ. "
"4- Maa maa jókòó ni iwaju rẹ pẹlu ẹkọ. "
"5- Maa tẹti si i daadaa ti mi o si nii ge ọrọ mọ ọn lẹnu nibi idanilẹkọ rẹ."
"6- Maa maa lo ẹkọ pẹlu bibeere ibeere."
"7- Mi o nii fi orukọ rẹ pe e."

"Ibeere 10: Ki ni awọn ẹkọ ààyè ìjókòó?"

"Idahun-1- Maa salamọ si awọn ti wọn wa ni ìjókòó."
"2- Maa jókòó si ibi ti ìjókòó naa ba pari si, mi o si nii gbe ẹnikẹni dide kuro ni ibùjókòó rẹ tabi pe ki n jókòó laarin awọn meji ayaafi pẹlu iyọnda wọn."
"3- Maa gba ẹlomiran láàyè láti jókòó."
"4- Mi o nii ja lu ọrọ ni ìjókòó."
"5- Maa gba iyọnda maa si salamọ ki n to kuro ni ìjókòó."
"6- Nígbà tí ìjókòó ba ti pari, maa ṣe adua kaffāratul Majlis (pipa ẹṣẹ ìjókòó rẹ)" "«Subhānaka Llāhummọ wabi hamdiKa, ash-hadu an lā ilāha illā Anta, astagfirukKa wa atūbu ilayKa»."

"Ibeere 11: Darukọ awọn ẹkọ oorun?"

"Idahun-1- Maa tete sun."
"2- Maa sun lori imọra."
"3- Mi o nii da ikùn dé ilẹ̀ sùn.
"4- Maa fi ẹgbẹ ọtun mi sun, maa wa gbe ọwọ ọtun mi si abẹ parikẹ ọtun mi."
"5- Maa gbọn ibusun mi."
"6- Maa ka awọn iranti oorun, bi Āyatul Kursiyyu, ati Sūratul Ikhlās, ati Al-Mu‘awidhatayn ni ẹẹmẹta mẹta. Maa wa sọ pe:" "«Bismika Llāhummọ amūtu wa ’ahyā»."
"7- Maa ji dide fun Irun Al-fajri."
"8- Maa wa sọ lẹyin ti mo ba ji lati oju oorun pe: "«Alhamdulillāhi lladhi ahyānā ba‘damā amātanā wa ilayhin nushūr»"

"Ibeere 12: Ki ni àwọn ẹkọ ounjẹ?"

"Idahun-"
"1- Maa ni aniyan pẹlu jijẹ ati mimu mi ìní agbára lori titẹle Ọlọhun Ọba ti O biyi ti O si gbọnngbọn."
2- "Fifọ ọwọ mejeeji ṣaaju jijẹ."
"3- Maa sọ pe: "BismiLlāh", maa si fi ọwọ ọtun mi jẹun ati ninu èyí tí o ba sunmọ mi, mi ò si nii jẹun ni aarin abọ, tabi ni iwaju ẹlomiran."
"4- Ti mo ba gbagbe lati darukọ Ọlọhun maa sọ pe: "Bismillāh awwalahu wa ākhirahu" "
"5- Maa yọnu si ounjẹ ti o ba wa, mi ò si nii fi aleebu kan ounjẹ, ti o ba wu mi maa jẹ ẹ, ti ko ba si wu mi maa fi i silẹ."
"6- Maa jẹ awọn okele diẹ, mi ò si ni jẹun pupọ."
"7- Mi o nii fẹ atẹgun si inu ounjẹ tabi nkan mimu, maa si fi i silẹ titi yio fi tutu."
"8- Maa ma jẹun papọ pẹlu awọn miran ninu awọn ara ile mi tabi alejo."
"9- Mi o nii bẹrẹ ounjẹ ṣaaju ẹlomiran ninu awọn ti wọn ju mi lọ."
"10- Maa darukọ Ọlọhun ti mo ba fẹ mu nkan, maa si mu un lori ìjókòó ni gẹ̀ẹ́ mẹta."
"11- Maa dupẹ fun Ọlọhun ti mo ba jẹun tan."

"Ibeere 13: Onka awọn ẹkọ wíwọ aṣọ?"

"Idahun-1- Maa bẹrẹ wíwọ aṣọ mi pẹlu ọtun, maa wa dupẹ fun Ọlọhun lori iyẹn."
"2- Mi o nii jẹ ki aṣọ mi o gun kọja kokosẹ mejeeji."
"3- Awọn ọmọkùnrin o gbọdọ wọ aṣọ awọn ọmọbinrin, bẹẹ si ni awọn ọmọbinrin o gbọdọ wọ aṣọ awọn ọmọkunrin."
"4- Ki o ma jọ aṣọ awọn keferi tabi awọn ẹlẹṣẹ."
"5- Ṣiṣe BismiLlāh nibi bibọ aṣọ."
"6- Wiwọ bata si ọtun ni akọkọ, ati bibọ ọ sílẹ̀ lati osi."

"Ibeere 14: Darukọ awọn ẹkọ gigun nkan ọ̀gùn?"

"Idahun-1- Maa sọ pe: «Bismillāh, Alhamdulillāhi»," "{Subhāna Llādhi sakhara lanā hādhā wa mā kunnā lahu muqrinīn 13" "{Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí 14}." [Suuratu Az-Zukhruf: 13, 14].
"2- Ti mo ba kọja lára musulumi kan; maa ki i. "

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogun: Dárúkọ awọn ẹkọ oju-ọna? "

"Idahun- 1- Maa duro déédéé, ma si tẹriba nibi irin mi, maa si maa rin ni ẹgbẹ ọtun oju-ọna. "
"2- Maa maa salamọ si gbogbo ẹni ti mo ba n pade. "
"3- Maa rẹ oju mi nilẹ, mi o si nii fi suta kan ẹnikẹni. "
"4- Maa maa paṣẹ pẹlu ohun rere, maa si maa kọ ohun buruku."
"5- Maa maa mu suta kuro ni oju-ọna. "

"Ibeere ẹlẹẹkerindinlogun: Dárúkọ awọn ẹkọ wiwọ inu ile ati jijade kuro nibẹ? "

"Idahun- 1- Maa jade pẹlu ẹsẹ mi òsì, maa wa sọ pe: " Bismillaah, tawakkaltu 'alaallahi, laa awla walaa quwwata illa billahi, Allahumo innii a'udhubika an adilla aw udọlla, aw azilla aw uzalla, aw azlima aw uzlama, aw ajhala aw yujhala alayya. 3- Maa wọle pẹlu ẹsẹ mi ọtun, maa maa sọ pe: Bismillahi walajnaa, wa bismillahi khorojnaa, wa 'alaa Robbinaa tawakkalnaa.
"3- Ati pe maa bẹrẹ pẹlu rirun pako, lẹyin naa maa ki awọn ara ile. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlogun: Dárúkọ awọn ẹkọ bibiya bukaata? "

"1- Maa wọle pẹlu ẹsẹ mi osi. "
"2- Maa maa sọ ṣíwájú wiwọle pe: “Bismillahi, Allahumo innii a'udhubika minal khubthi wal khobaahith”.
"3- Mi ko nii wọle pẹlu nnkankan ti iranti Ọlọhun n bẹ nibẹ."
4- Maa fi ara pamọ ti mo ba n gbọ bukaata lọ́wọ́.
5- Mi ko nii sọrọ ni aaye bibiya bukaata. "
"6- Mi o nii kọju si qiblah mi o si nii kọ ẹyin si i ti mo ba n tọ tabi ti mo ba n ya igbẹ."
"7- Maa lo ọwọ osi mi lati fi mu ẹgbin kuro, mi o si nii lo ọwọ ọtun."
"8- Mi o nii ya igbẹ tabi tọ̀ si oju-ọna awọn eeyan tabi abẹ iboji wọn."
"9- Maa fọ ọwọ mi lẹ́yìn tí mo ba yagbẹ tabi tọ̀ tán.
"10- Maa gbe ẹsẹ osi mi jade, maa wa sọ pe: "Gufrānak"."

"Ibeere 18: Darukọ awọn ẹkọ masalasi?"

"Idahun-1- Maa gbe ẹsẹ ọtun mi wọ inu masalasi maa wa sọ pe:" "«BismiLlāh, Allāhummọ iftah lī abwāba rahmatiKa»."
"2- Mi o nii jókòó titi maa fi ki rakah meji."
"3- Mi o nii gba iwaju awọn to n kirun kọja, mi o si nii kéde nkan ti o ba sọnu ninu masalasi, mi o si nii ta mi o nii ra ninu masalasi."
"4- Maa gbe ẹsẹ osi mi jade lati inu masalasi maa wa sọ pe:" "«Allāhummọ innī as’aluKa min fadliKa»."

"Ibeere19: Darukọ awọn ẹkọ salamọ?"

"Idahun-1- Ti mo ba pade Musulumi kan, maa kọkọ salamọ si i, pẹlu gbolohun: «As salāmu alaykum wa rahmotulloohi wa barakaatuhu» ko nii jẹ nkan ti o yatọ si salamọ, mi o si nii ṣe itọka pẹ̀lú ọwọ mi nikan."
"2- Maa rẹẹrin si ẹniti mo ba salamọ si."
"3- Maa si tun bọ ọ lọwọ pẹlu ọwọ ọtun mi."
"4- Ti ẹnikẹni ba ki mi pẹlu kiki kan, maa ki i pẹlu eyiti o daa ju u lọ, tabi ki n da iru rẹ pada."
"5- Mi o nii kọkọ salamọ si keferi, ti o ba si salamọ si mi maa da a loun pẹlu iru rẹ."
"6- Ọmọde a salamọ si agbalagba, ẹniti n gun nkan a salamọ si ẹniti n rin, ẹniti n ri a salamọ si ẹniti o jókòó, awọn to kere a salamọ si awọn to pọ̀."

"Ibeere 20: Darukọ awọn ẹkọ gbigba iyọnda?"

"Idahun-1- Maa gba iyọnda ṣíwájú ki n to wọle si aaye náà."
"2- Maa gba iyọnda ni ẹẹmẹta ti mi o si nii fi kun un, lẹyin naa maa kuro."
"3- Maa kan ilẹkun pẹlu pẹlẹpẹlẹ, mi o si nii duro si ọ̀ọ́kán ilẹkun, bi ko ṣe wipe maa duro si ọtun rẹ tabi osi rẹ."
"4- Mi o nii wọ yàrá baba mi tabi iya mi tabi ẹnikẹ́ni ṣíwájú iyọnda, agaga julọ ni asiko Al-fajri ati asiko qaylūlah (oorun ọsan), ati ni ẹyin Ishai."
"5- O rọrun ki n wọ awọn aaye ti wọn kò gbe ibẹ̀, bii: Ilé iwosan tabi ile itaja lai gba iyọnda."

"Ibeere 21: Darukọ awọn ẹkọ siṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu awọn ẹranko?"

"Idahun-1- Maa fun ẹranko ni jijẹ maa si tun fun un ni mimu."
"2- Ṣiṣe ikẹ ati aanu pẹlu ẹranko, ati ima maa gbe nkan ti agbara rẹ o ka le e lori."
"3- Mi o nii fi iya jẹ ẹranko pẹlu eyikeyi iran iya ati suta."

"Ibeere 22: Darukọ awọn ẹ̀kọ́ ti n bẹ fun ere idaraya?"

"Idahun-1- Maa gbero pẹlu ere idaraya ìní agbára torí itẹle Ọlọhun ati iyọnu Rẹ."
"2- A ko nii ṣeré ni asiko Irun."
"3- Awọn ọmọkunrin o nii ṣe ere idaraya pẹlu awọn ọmọbinrin."
"4- Maa dunni mọ aṣọ ere idaraya ti o bo ihoho mi."
"5- Maa jina si awọn ere idaraya ti o jẹ eewọ, bii èyí tí gbigba oju ati ṣiṣi ihoho ara silẹ wa níbẹ̀."

"Ibeere 23: Darukọ diẹ ninu awọn ẹkọ awada?"

"Idahun-1- Sisọ ootọ nibi awada, ki o si ma ni irọ ninu."
"2- Awada ti ko ni iyẹpẹrẹ ati yẹyẹ ati iṣeninisuta ati idẹruba ninu."
"3- Ki awada o ma pọ ju."

"Ibeere 24: Darukọ awọn ẹkọ sisin?"

"Idahun-1- Gbigbe ọwọ tabi aṣọ tabi aṣọ pelebe ìnujú si imu nígbà tí a ba sin."
"2- Ki o dupẹ fun Ọlọhun lẹyin sisin pe «AlhamduliLlāh»."
"3- Ki ọmọ-ìyá rẹ tabi ọrẹ rẹ o sọ fun un pe: «Yarhamuka Llāhu»."
"Ti o ba ti wa sọ bẹẹ fun un:
ki o yaa sọ pe: «Yahdīkumu Llāhu wa yuslihu bālakum»."

"Ibeere 25: Ki ni àwọn ẹkọ yiyan?"

"Idahun-1- Gbigba iyanju lati dá yiyan padà."
"2- Ima maa gbe ohun sókè pẹlu sisọ pe "aah" aah"."
"3- Gbigbe ọwọ le ẹnu."

"Ibeere 26: Sọ awọn ẹkọ kika (Al-Qur'āni)?"

"Idahun-1- Kika lori imọra lẹyin aluwala."
"2- Jíjókòó pẹlu ẹkọ ati ibalẹ ara."
"3- Maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ Shaytān ni ibẹrẹ kika."
"4- Maa ronu si kika naa"

"Ipin àwọn iwa"30

"Ibeere 1: Sọ ọla ti n bẹ fun iwa rere?"

"Idahun: Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "«Ẹniti o pe julọ ni igbagbọ ninu awọn Mu'mini ni ẹniti o dara julọ ni iwa." Tirmiziy ati Ahmad ni won gba a wa

"Ibeere 2: Ki nìdí ti a maa fi dunni mọ awọn iwa Isilaamu?"

"Idahun-1- Nítorí pé o jẹ okunfa ifẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga."
"2- O tun jẹ okunfa ifẹ awọn ẹda."
"3- O si tun jẹ nkan ti o wuwo ju ninu oṣuwọn."
"4- Laada ati ẹsan si maa n jẹ adipele pẹlu iwa daadaa."
"5- O si tun jẹ ami fun pipe ìgbàgbọ́."

"3- Nibo ni a ti maa mu awọn ìwà?"

"Idahun- Ninu Kuraani Alapọn-ọnle, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà}" [Suuratul-Israa: 9]. "Ninu ọrọ ojiṣẹ Ọlọhun: Nibi ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti sọ pe: " “Dájúdájú wọn gbe mi dide lati pe awọn eyi to daa ninu awọn iwa”. Ahmad ni o gba a wa "

"Ibeere kẹrin: Ki ni iwa dáadáa ati awọn aworan ẹ? "

"Idahun- iṣe dáadáa: Oun ni sisọ Ọlọhun ni gbogbo igba, ati ṣiṣe dáadáa ati dáadáa fun àwọn ẹda. "
"Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Dájúdájú Ọlọhun ti kọ dáadáa lori gbogbo nnkan” Muslim ni o gba a wa.
"Ninu awọn aworan ṣiṣe dáadáa ni:
"
1388."Ṣiṣe dáadáa nibi ijọsin fun Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, iyẹn jẹ pẹlu imọkanga nibi ijọsin Rẹ. "
"Ṣiṣe dáadáa si awọn obi mejeeji, pẹlu ọrọ ati iṣẹ. "
"Ṣiṣe dáadáa si awọn ẹbi ati alasunmọ "
"Ṣiṣe dáadáa si aládùúgbò
"Ṣiṣe dáadáa si awọn ọmọ-orukan ati awọn mẹkunnu"
"Ṣiṣe dáadáa si ẹni ti o n ṣe aburu si ẹ"
"Ṣiṣe dáadáa nibi ọrọ"
Ṣiṣe dáadáa nibi atako "
"Ṣiṣe dáadáa si ẹranko "

"Ibeere karun-un: Ki ni idakeji ṣiṣe dáadáa? "

"Idahun- Idakeji ṣiṣe dáadáa ni ṣíṣe aida. "
*Ninu iyẹn ni:
Gbígbé imọkanga ju silẹ nibi ijọsin fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga
"Ṣiṣẹ obi mejeeji "
Gige okun ebi.
Aladugboo buruku
"*Ati gbigbe ṣiṣe daadaa si awọn talaka ati alaini ju silẹ, ati eyiti o yatọ si iyẹn ninu awọn ọrọ ati iṣẹ buruku."

"Ibeere 6: Ki ni awọn ìran ifọkantan ati awọn aworan rẹ?"

"Idahun-"
"1- Ifọkantan nibi sisọ awọn iwọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga."
"Awọn aworan rẹ:
Ifọkantan nibi pipe awọn ijọsin bi Irun, ati Zakah, ati Aawẹ, ati Hajj, ati eyiti o yatọ si wọn ninu awọn nkan ti Ọlọhun ṣe ni ọranyan le wọn lori."
"Ifọkantan nibi sisọ awọn iwọ awọn ẹda:
"
"Nibi sisọ ijẹ-ọmọluabi awọn eeyan."
"Ati awọn dukia wọn."
"Ati awọn ẹjẹ wọn."
"Ati awọn kọkọ wọn, ati gbogbo nkan ti awọn eeyan ba fi ọkan balẹ si ọ lọdọ lori rẹ."
"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nibi awọn iroyin awọn olujere pe:
" "{àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn 8}" [Suuratul-Mu’minuun: 8].

"Ibeere 7: Ki ni idakeji Ifọkantan?"

"Idahun- Ijanba, oun naa ni rira awọn iwọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati awọn iwọ awọn eeyan lare."
"Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "«Ami Munaafiki mẹta ni» - o wa darukọ ninu rẹ pe - «Ti wọn ba fi ọkan tan an yio janba» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere 8: Ki ni o n jẹ iwa ododo?"

"Idahun- Oun ni ifunni ni iro pẹlu nkan ti yio ba nkan ti o n ṣẹlẹ mu tabi nipa nkan gẹgẹ bi o ṣe wa."
"Ati pe ninu awọn aworan rẹ ni:

"Sisọ ododo nibi isọrọ pẹlu awọn eeyan."
"Sisọ ododo nibi adehun."
"Sisọ ododo nibi gbogbo ọrọ ati iṣe. "
"Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Dajudaju ododo maa n tọ ni sọna sibi dáadáa, ati pe dajudaju dáadáa maa n tọ ni sọna sinu alujanna, ati pe dajudaju eniyan a maa sọ ododo titi ti o fi maa di olódodo” Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere kẹsan-an: Ki ni idakeji ododo? "

"Idahun- Irọ, òun ni idakeji ododo, ninu iyẹn ni, pipa irọ mọ awọn eniyan, ati yiyapa awọn adehun, ati jijẹrii eke. "
"Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ati pe dajudaju irọ maa n tọ ni sọna sibi iwa aburu, dajudaju iwa aburu maa n tọ ni sọna sinu ina, ati pe dajudaju eniyan a maa pa irọ titi ti o fi maa di onirọ lọdọ Ọlọhun”. Wọn fi ẹnu ko le e lori. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Àmì ṣọbẹ-ṣelu musulumi, mẹta ni” -o darukọ ninu ẹ- “Ti o ba sọrọ, yoo pa irọ, ti o ba ṣe adehun yóò yapa”. Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere kẹwaa: Dárúkọ awọn iran suuru? "

"Idahun- Ṣíṣe suuru lori itẹle ti Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
Ṣíṣe suuru kuro nibi ẹṣẹ "
Ṣíṣe suuru lori kádàrá Ọlọhun to mu inira dani, ati di dupẹ fun Ọlọhun lori gbogbo iṣesi."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù 146}." "[Surah Âl-`Imrân: 146]" "Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Eemọ ni fun alamọri olugbagbọ, dajudaju gbogbo alamọri rẹ pátápátá jẹ dáadáa, iyẹn ko si fun ẹnikẹni afi fun olugbagbọ; ti idunnu ba ṣẹlẹ si i o maa dupẹ, ìyẹn si maa lóore fun un, ti inira ba ṣẹlẹ si i o ma ṣe suuru, ìyẹn sì maa jẹ oore fun un. Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere ẹlẹẹkọkanla: Ki ni idakeji suuru? "

"Idahun- Oun ni aiṣe suuru lori itẹle, ati aiṣe suuru kuro nibi ẹṣẹ, ati aiyọnu si awọn kádàrá Ọlọhun pẹlu ọrọ ati iṣẹ. "
"Ninu awọn aworan ẹ:
"
"Imaa tanmọọn iku."
"Imaa gba ara ẹni ni oju."
"Imaa fa aṣọ ya."
"Imaa tu irun ka si ori (latari fifi ibanujẹ hàn)."
"Imaa ṣe adua iparun lori ara ẹni."
"Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "Ẹsan n bẹ pẹlu titobi adanwo, ati pe dajudaju ti Ọlọhun ba nífẹ̀ẹ́ ijọ kan yio dan wọn wo, ẹniti o ba yọnu, iyọnu o maa jẹ tiẹ, ẹniti o ba si binu, ibinu o maa jẹ tiẹ." "Tirmidhiy ati Ibnu Mājah ni wọn gba a wa."

"Ibeere 12: Darukọ iwa ikunlọwọ?"

"Idahun- Oun naa ni ki awọn eeyan maa ṣe ikunlọwọ laarin ara wọn lori ododo ati daadaa."
"Awọn aworan iṣe ikunlọwọ:
"
"Iṣe ikunlọwọ lori dida awọn ẹtọ pada."
"Iṣe ikunlọwọ lori dida alabosi ni ọwọ kọ."
"Iṣe ikunlọwọ lori bibiya bukaata awọn eeyan ati awọn alaini."
"Iṣe ikunlọwọ lori gbogbo daadaa."
" Ima maa ṣe ikunlọwọ lori ẹsẹ ati ṣiṣe suta ati ikọja aala."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-àlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.}" "[Sūratul Mā’idah: 2]." "Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "«Mu’mini si Mu'mini da bii ile ni; ti apakan o maa fun apakan ni agbara» " Wọn fi ẹnu ko le e lori. "Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - tun sọ pe:" "«Musulumi ọmọ-ìyá Musulumi ni, ko nii ṣe abosi rẹ, ko si nii fa a kalẹ fun ẹniti yio fi ara ni i, ẹniti o ba si n biya bukaata ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun a maa biya bukaata tiẹ naa, ẹniti o ba si mu ibanujẹ kuro fun musulumi kan, Ọlọhun a mu kuro fun un ibanujẹ kan ninu awọn ibanujẹ ọjọ igbedide, ẹniti o ba si bo musulumi kan ni aṣiri, Ọlọhun a bo oun naa ni aṣiri ni ọjọ igbedide» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Ki ni awọn iran iwa itiju? "

"Idahun- 1- Ìtìjú Ọlọhun: Yoo maa wáyé pẹ̀lú pe ki o ma maa ṣẹ Ẹ -mimọ ni fun Un-. "
"2- Itiju awọn eniyan: Nínú iyẹn ni gbigbe ọrọ buruku ti ko dara ju silẹ ati ṣiṣi ihoho silẹ. "
"Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " Igbagbọ ni ẹka aadọrin ati diẹ tabi ọgọta ati diẹ, eyi to ga julọ nibẹ ni gbólóhùn: Laa ilaaha illallohu. Eyi to kere julọ nibẹ: Mímú suta kuro ni oju-ọna,ati pe itiju jẹ ẹka kan ninu igbagbọ”. Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinla: Darukọ awọn aworan iwa àánú? "

"Idahun- 1- Ṣíṣe ikẹ awọn agbalagba ati ṣiṣe apọnle wọn. "
"2- Ṣíṣe ikẹ awọn ọmọde ati awọn oponlo. "
"3- Ṣíṣe ikẹ alaini ati mẹkunnu ati ẹni ti o ni bukaata. "
"4- Ṣíṣe ikẹ ẹranko pẹlu pe ki o maa fun un ni ounjẹ ki o si ma fi suta kan an. "
"Ninu iyẹn ni ọrọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: " Waa ri awọn olugbagbọ nibi ṣiṣe ikẹ ara wọn ati nini ifẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn, wọn da gẹgẹ bi ara, ti orikee kan ba ké ìrora, awọn orikee yoku a maa pe ara wọn fun un pẹlu aisun ati iba”. Wọn fi ẹnu ko le e lori. "Ati pe Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " Àwọn onikẹẹ, Ọba Ajọke-aye a maa kẹ wọn, ẹ maa ṣe ikẹ awọn ara ilẹ, Ẹni ti O wa ni sanmọ a maa kẹ yin”. "Abu Daud ati Tirmidhi ni wọ́n gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogun: Ki ni awọn iran iwa ifẹ? "

"Idahun- Níní ifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí}." "[Surah Al-Baqarah: 165]"
"Nini ifẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "
o so pe:
“Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ninu yin o ni tii di olugbagbọ titi maa fi di ẹni ti o ni ifẹ si ju obi rẹ ati ọmọ rẹ lọ”. "Al-Bukhāriy ni o gba a wa."
"Nini ifẹ awọn Mu'mini, ati nini ifẹ daadaa fun wọn gẹgẹ bi o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ fun ara rẹ."
"Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "«Ẹnikẹni ninu yin o le tii pe ni igbagbọ titi ti yio fi maa fẹ fun ọmọ-ìyá rẹ nkan ti n fẹ fun ara rẹ»" "Al-Bukhāriy ni o gba a wa."

"Ibeere 16: Ṣe alaye nkan ti n jẹ Al-Bashāshatu?"

"Idahun- Oun ni titu oju ka, pẹlu idunnu ati ririn ẹrin musẹ, ati aanu ati fifi idunnu han nígbà tí a ba pade awọn eeyan."
"Ati pe oun jẹ idakeji lile oju mọ awọn eeyan ni èyí tí yio maa le wọn sa."
"Ati pe awọn hadīth ti o pọ ti wa nipa ọla iyẹn, lati ọdọ Abu Dharri - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ fun mi pe:" "«Ma fi oju kere nkankan ninu daadaa, koda ki o pade ọmọ-ìyá rẹ pẹlu titu oju ka» " Muslim ni o gba a wa. "Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun sọ pe:" "«Ririn ẹrin musẹ loju ọmọ-ìyá rẹ, saara ni fun ọ» " Tirmidhiy ni o gba a wa

"Ibeere 17: Ki ni n jẹ Hasad (Keeta)?"

"Idahun- Oun ni ti tanmọọn yiyẹ idẹra kuro lọdọ ẹlomiran tabi kikorira idẹra ẹlomiran."
"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
{Àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara 5} [Sūratul Falaq: 5]."
" Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:" "«Ẹ ma korira ara yin, ẹ ma ṣe keeta ara yin, ẹ ma kọyin si ara yin, ẹ jẹ - ẹyin ẹrusin Ọlọhun - ọmọ-ìyá» " "Al-Bukhāriy ati Muslim ni wọn gba a wa."

"Ki ni n jẹ Al-’Istihzāh?"

"Idahun- Oun ni yi yẹyẹ ọmọ-iya rẹ to jẹ musulumi ati iyẹpẹrẹ rẹ, eleyii ko lẹ́tọ̀ọ́."
"Ọba ti ọla Rẹ sọ nibi kikọ kuro nibi iyẹn:
" "{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (t’ó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín lóríkì burúkú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn alábòsí. 11}" [Suuratul-Hujuraat 11].

"Ibeere 19: Ṣe alaye nkan ti n jẹ Itẹriba?"

"Idahun- Oun ni ki ọmọniyan o ma maa ri ara rẹ lori awọn eeyan, ki o si ma maa yẹpẹrẹ awọn eeyan, ki o si ma maa kọ ododo."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn t’ó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀} " [Suuratul-Furqan: 63]. "Itumọ rẹ ni: Ni àwọn tí wọ́n n tẹrí bá." "- Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun sọ pe:" "«Ẹnikankan o si nii rẹ ara rẹ silẹ fun Ọlọhun ayaafi ki Ọlọhun gbe e ga» " Muslim ni o gba a wa. "O tun sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe:" "«Dajudaju Ọlọhun ranṣẹ si mi wipe ki ẹ tẹriba, debi wipe ẹnikankan o nii maa ṣe iyanran lori ẹnikẹni, ẹnikankan o si nii maa tayọ aala lori ẹnikẹni» " Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 20: Ki ni awọn iran igberaga ti o jẹ eewọ?"

"Idahun-1- Ṣiṣe igberaga nibi ododo, oun naa ni dida a pada ati ai gba a wọle."
"2- Ṣiṣe igberaga si awọn eeyan, oun naa ni iyẹpẹrẹ wọn, ati fifi oju kere wọn."
"Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:" "«Ko nii wọ al-Jannah, ẹni tí deedee ọmọ ina-igun ninu igberaga ba wa ni ọkan rẹ»." "Ni arakunrin kan ba sọ pe: Dajudaju ọmọkunrin a maa nífẹ̀ẹ́ si ki aṣọ rẹ o yaayi ki bata rẹ naa o si dara? O sọ pe:" "«Dajudaju Ọlọhun Ọba, Arẹwa ni, O si nífẹ̀ẹ́ si nkan ti o ba rẹwa, nkan ti n jẹ igberaga ni: kikọ ododo, ati iyẹpẹrẹ awọn eeyan» " Muslim ni o gba a wa.
"- Batarul Haqqi: Dida a pada"
"- Gamtun Nās: Yiyẹpẹrẹ wọn"
"- Aṣọ ti o dara ati bata ti o dara o si ninu igberaga."

"Ibeere 21: Darukọ apakan ninu awọn irẹjẹ ti o jẹ eewọ?"

"- Irẹjẹ nibi kata-kara, oun naa ni fifi aleebu ọja pamọ."
"- Irẹjẹ nibi kikọ imọ, apejuwe iyẹn ni irẹjẹ awọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ninu idanwo."
"- Irẹjẹ nibi ọrọ sisọ, gẹ́gẹ́ bíi ijẹrii eke ati irọ pipa.'
"- Aipe adehun pẹlu nkan ti o sọ ati nkan ti o fi ẹnu ko pẹlu awọn eeyan lori rẹ."
"O si ti wa nibi kikọ kuro nibi irẹjẹ pe, dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi okiti ounjẹ kan, o wa ti ọwọ rẹ bọ inu rẹ, ni awọn ọmọnika rẹ ba kan nkan tutu kan, ni o ba sọ pe: «Ki ni eyi irẹ oni ounjẹ?» o sọ pe: Ojo ni o pa a irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun. O sọ pe:" "«Oo ṣe jẹ́ ki o wa lókè ounjẹ ki awọn eeyan le baa ri i? Ẹnikẹni ti o ba ṣe irẹjẹ ko si ni ara mi» " Muslim ni o gba a wa.
"As-Subrọ: Oun ni okiti ounjẹ."

"Ibeere 22: Ki ni n jẹ Al-Gībah (Ọrọ ẹyin)?"

"Idahun- Oun ni didarukọ ọmọ-ìyá rẹ musulumi pẹlu nkan ti o korira ti oun ko si si nibẹ."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ t’ó ti kú ni? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run 12}" [Suuratul-Hujuraat 12].

"Ibeere 23: Ṣe alaye An-Namīmah (Òfófó)?"

"Idahun- Oun ni gbigbe awọn ọrọ kiri laarin awọn eeyan lati da ibajẹ silẹ laarin wọn."
"- Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:" "«Olofofo ko nii wọ al-Jannah»" Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 24: Ki ni n jẹ Al-Kasal (oju riro)?"

"Idahun- Oun ni kíkàndí mọ́lẹ̀ nibi ṣiṣe iṣẹ oloore ati nkan ti ṣiṣe rẹ jẹ dandan fun ọmọniyan."
"Ati pe ninu iyẹn ni:
Ìmẹ́lẹ́ nibi ṣiṣe awọn ọranyan."
"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
" "{Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀ 142}" "[Sūratun Nisā'i: 142]."
"Nitori naa o lẹ́tọ̀ọ́ fun Mu'mini gbigbe imẹlẹ ati aileṣiṣẹ, ati ijokoo tẹtẹrẹ ju silẹ, o si tun lẹ́tọ̀ọ́ fun un igbiyanju nibi iṣẹ ati lilọ bibọ ati ṣiṣe wahala ati gbigba iyanju ninu aye sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ninu."

"Ibeere 25: Darukọ awọn iran ibinu?"

"Idahun- 1- Ibinu ti o dara: Oun ni ki o jẹ fun Ọlọhun nigba ti awọn alaigbagbọ tabi awọn ṣọbẹ-ṣelu musulumi tabi ẹni ti o yatọ si wọn ba fa awọn ọgba eewọ Ọlọhun -mimọ ni fun Un- ya. "
"2- Ibinu ti ko dara: Oun ni ibinu to jẹ pe o maa n mu eniyan ṣe ati sọ nnkan ti ko tọ. "
"Iwosan ibinu ti ko dara:
"
"Aluwala. "
"Jíjókòó ti o ba wa ni iduro, ati fifi ẹgbẹ le ilẹ ti o ba wa lori ìjókòó. "
"Ki o dunni mọ asọtẹlẹ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi ìyẹn: “O o gbọdọ maa binu”.
“Ki o ko ẹmi rẹ ni ìjánu lati ma yára ṣe nǹkan ti ìbínú ba n ti i lati ṣe ni àsìkò ìbínú”
"Wiwa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọ́dọ̀ eṣu ẹni ẹkọ. "
Didakẹ

Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlọgbọn: Ki ni o n jẹ itọpinpin? "

"Idahun- Oun ni afihan ati iwadii nipa awọn ihoho awọn eniyan ati nnkan ti wọn n bo. "
"Ninu awọn aworan ẹ ti a ṣe ni eewọ ni:
"
Wíwo ihoho awọn eniyan ninu awọn ile wọn. "
Ki eniyan maa tẹti gbọ ọrọ awọn ijọ kan ti wọn ko si mọ̀ si i. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín...}." [Suuratul-Hujuraat 12].

"Ibeere ẹlẹẹketadinlọgbọn: Ki ni o n jẹ ina-apa? Ki si ni o n jẹ ahun? Ki ni o n jẹ ọrẹ?"

"Idahun- ina-apa: Oun ni nina owo ni ọna ti ko lẹtọọ,"
Idakeji ẹ:
Ahun: Oun ni ki eeyan ma ṣe ẹtọ rẹ fun un.
"Eyi to tọ ni wiwa laarin mejeeji, ki musulumi si jẹ ọlọrẹ. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì 67}. " "[Surah Al-Furqan : 67]"

"Ibeere ẹlẹẹkejidinlọgbọn: Ki ni o n jẹ ojo? Ki si ni o n jẹ igboya? "

"Idahun- Al-Jubnu (Ojo): Ni ki o maa bẹru nkan ti ko tọ ki eeyan o bẹru."
"Gẹgẹ bíi pipaya sisọ ododo ati kikọ ibajẹ."
"Ash-Shajā‘ah (Akin): Oun naa ni gbigba iwaju nibi òdodo, iyẹn ni bii gbigba iwaju ni awọn ojude ija ẹsin lati da aabo bo Isilaamu ati awọn Musulumi."
"Ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n sọ ninu adua rẹ pe:" "«Allāhummọ innī a‘ūdhu biKa minal jubni...»." "Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun sọ pe:" "«Mu'mini to ni agbara loore, o si tun jẹ ẹniti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mu'mini to jẹ ọlẹ lọ, ati pe oore n bẹ lara ọkọọkan wọn." Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 29: Darukọ diẹ ninu awọn ọrọ ẹnu ti o jẹ eewọ?"

"Idahun- Gẹgẹ bii epe ati eebu."
"- Gẹgẹ bii gbolohun wipe “lagbaja ẹranko ni" tabi èyí tí o jọ ọ ninu awọn gbolohun."
"- Tabi didarukọ awọn ihoho pẹlu awọn ọrọ buruku ati ọrọkọrọ."
"- Ati pe Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti kọ kuro nibi gbogbo iyẹn patapata, nitori naa ni o fi sọ pe: "Mu'mini o ki n ṣe ẹni tí maa n yọ aleebu ara eeyan, ko si ki n ṣe ẹni tí maa n ṣepe, ko si ki n ṣe oni ọrọ buruku, ko si ki n ṣe ẹlẹnu jijo (ti ko si ọrọ ti ko le sọ)." "Tirmidhiy ati Ibnu Hibbān ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 3: Darukọ awọn okunfa kan ti maa n ran musulumi lọwọ lati maa wu iwa rere?"

"Idahun- Ṣiṣe adua wipe ki Ọlọhun rọ ọ ni ọrọ iwa rere, ki O si tun ran ọ lọwọ lori rẹ."
"2- Imaa sọ Ọlọhun Ọba ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ati pe O mọ ọ, O si n gbọ ọ, O si n ri ọ."
"3- Imaa ranti ẹsan iwa rere ati pe oun ni okunfa wiwọ al-Jannah."
"4- Imaa ranti àtúbọ̀tán iwa buruku ati pe oun ni okunfa wiwọ ina."
"5- Dajudaju iwa rere maa n fa ifẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati ifẹ awọn ẹda Rẹ, ati pe dajudaju iwa buruku maa n fa ikorira Ọlọhun ati ikorira awọn ẹda Rẹ."
"6- Kika itan Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - ati wiwo o kọṣe."
"7- Mimaa ba awọn ẹnirere sọrẹ, ati jijina si biba awọn ẹni burúkú sọrẹ."

"Ipin awọn adua ati awọn iranti"43

"Ibeere 1: Ki ni ọla ti n bẹ fun iranti (Ọlọhun)?"

"Idahun- Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:" "«Apẹrẹ ẹni tí n ranti Oluwa rẹ ati ẹni tí ko ki n ranti Oluwa rẹ, apẹrẹ alaaye ati oku ni» ". "Al-Bukhāriy ni o gba a wa."
"- Eleyii ri bẹ́ẹ̀ nitori pe pàtàkì isẹmi ọmọniyan n bẹ pẹlu odiwọn iranti rẹ fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga."

"Ibeere 2: Darukọ díẹ̀ nínú awọn anfaani iranti (Ọlọhun)?"

"Idahun-1- Yio maa yọ Ọba Ar-Rahmān ninu."
"2- Yio tun maa le Shaytān jina."
"3- Yio si tun maa da aabo bo musulumi kuro nibi awọn aburu."
"4- Ẹsan ati laada o maa ti ara rẹ wa."

"Ibeere 3: Ki ni iranti to ni ọla julọ?"

"Idahun- «Lā ilāha illā Allāhu» " "Tirmidhiy ati Ibnu Mājah ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 4: Ki ni waa sọ ti o ba ji lati oju orun?"

"Idahun- «AlhamduliLāhi Lladhī ’ahyānā ba‘da mā amātanā' wa ilayHi nushūr» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere 5: Ki ni waa sọ ti o ba wọ aṣọ rẹ?"

"Idahun- «AlhamduliLlāhi Lladhī kasānī hādha thaoba wa rọzaqanīhi min gayri haolin minnī walā quwwah» " "Abū Dāud ati Tirmidhiy ati ẹlomiran yatọ si wọn ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 6: Ki ni waa sọ ti o ba bọ aṣọ?"

"Idahun- «BismiLlāhi» " Tirmidhiy ni o gba a wa

"Ibeere 7: Ki ni adua wiwọ aṣọ titun?"

"Idahun- «Allāhummọ laKal hamdu Anta kasaoTanīhi, as’aluka khayrahu wa khayra mā suniha lahu, wa a‘ūdhu biKa min sharrihi wa sharri mā suniha lahu» " "Abu Dāud ati Tirmidhiy ni o gba a wa."

"Ibeere kẹjọ: Ki ni adura ti ẹni ti o ba fẹ wọ aṣọ tuntun maa ṣe? "

"Idahun- Ti o ba ri aṣọ tuntun lọrun ẹlòmíràn, waa ṣe adura fun un, waa sọ pe: " “Tublii wa yukhlifullahu Ta'aalaa”. Abu Daud ni o gba a wa.

"Ibeere kẹsan-an: Dárúkọ adura iwọ inu ile-ẹgbin, oun ni aaye ibiiya bukaata? "

"Idahun- “Allahumo innii 'audhu bika minal khubthi wal khobaahith”. Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere kẹwaa: Ki ni adura jijade kuro lati inu ile-ẹgbin? "

"Idahun- “Gufrọọnaka”. "Abu Daud ati Tirmidhi ni wọ́n gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkanla: Ki ni waa sọ ṣíwájú aluwala? "

"Idahun- “Bismillaah” "Abu Daud ati ẹni ti o yatọ si i ni wọ́n gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkejila: Ki ni iranti ti a maa ka nigba ti a ba pari aluwala? "

"Idahun- “Ash’hadu an laa ilaaha illallohu wahdahu laa shareeka lahu, wa ash-adu anna Muhammadan 'abduhu wa rosuuluhu”. Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Ki ni iranti ti a maa ka ti a ba n jade nile? "

"Idahun- “Bismillah, tawakkaltu 'alaallahi, wa laa awla wa laa quwwata illaa billahi”. Abu Daud ati Tirmidhi ni o gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹrinla: Ki ni iranti ti a ba wọ inu ile? "

"Idahun- “Bismillah walajnaa, wa bismillah khorojnaa, wa 'alaallahi Robbinaa tawakkalnaa", lẹyin naa ki o salamọ si awọn ara ile rẹ”. Abu Daud ni o gba a wa.

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogun: Ki ni adura wiwọ inu mọsalasi? "

"Idahun- “Allahumo iftah lii abwaaba rahmotika”, Muslim ni o gba a wa. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlogun: Dárúkọ adura jijade lati inu mọsalasi? "

"Idahun- «Allāhummọ innī as’aluKa min fadliKa» Muslim ni o gba a wa."

"Ibeere 17: Ki ni waa sọ ti o ba n gbọ ipe Irun?"

"Idahun- Maa maa sọ iru nkan ti aperun ba n sọ ayaafi nibi: «Hayya ‘alas solaat» ati «Hayya ‘alal falāh» ma sọ pe: «Lā haola walā quwwata illā bilLāh» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere 18: Ki ni waa sọ lẹyin ipe Irun?"

"Idahun- (Waa ṣe asalaatu fun Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)" Muslim ni o gba a wa. "Wa waa sọ pe: «Allāhummọ robba hādhihid da‘watit tāmah was solaatil qā’imah, Āti Muhammadanil wasīlata wal fadīlah, wab‘ath'hu maqāman mahmūdanil ladhī wa‘adTahu» " "Al-Bukhāriy."
"Wa ṣe adua laarin ipe Irun ati iqāmah; torí pé wọn o nii da adua naa pada."

"Ibeere 19: Ki ni waa sọ ni aarọ ati ni irọlẹ ninu awọn iranti (Ọlọhun)?"

"Idahun-1- Ka āyatal Kursiyyu:" "{Allāhu lā ilāha illā Uwa Al-Hayyu Al-Qoyyūm lā ta’khudhuHu sinatun walā naom laHu mā fis samāwāti wa mā fil ardi man dha lladhī yashfa‘u ‘indaHu illā bi idhniHi Ya‘lamu mā bayna aydīhim wa mā khalfahum walā yuhītūna bi shay’in min ‘ilmiHi illā bimā Shā’a wasi‘a kursiyyuHus samāwāti wal ardọ walā ya’ūduHu hifdhuhumā wa Huwal Aliyyil ‘Adhīm 255}" "[Sūratul Baqorah: 255]." Ki o waa ka: "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" "{Qul Uwa Allāhu Ahad 1" "Allāhus Sọmad 2" "Lam yalid wa lam yūlad 3" "Walam yakun lahu kufuwan ahad 4}" "Ni ẹẹmẹta." "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" "{Qul a‘ūdhu bi robbil falaqi 1" "Min sharri mā khalaqa 2" "Wa min sharri gāsiqin idhā waqaba 3" "Wa min sharrin naffāthāti fil ‘uqad 4" "Wa min sharri hāsidin idhā hasada 5}" "Ẹẹmẹta" "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" "{Qul a‘ūdhu bi robbin nās 1" "Malikin nās 2" "Ilāhin nās 3" "Min sharril waswāsil khannās 4" "Alladhī yuwaswisu fī suduurin nās 5" "Minal jinnati wan nās 6}" "Ẹẹmẹta." "«Allāhumma Anta Robbī lā ilāha illā Anta, khalaqTani wa ana ‘abduKa, wa anā ‘alā ‘ahdiKa wa wa‘diKa mastata‘tu, a‘ūdhu biKa min sharri mā sọnah’tu, ’abū’u laKa bi ni‘matiKa alayya, wa ’abū’u bi dhambī, fagfirlii, fa innahu lā yagfirudh dhunūba illā Anta» ' "Al-Bukhāriy ni o gba a wa."

"Ibeere 20: Ki ni waa sọ ti o ba fẹ sun?"

"Idahun- «BismiKa Llāhumma amūtu wa ahyā» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere 21: Ki ni waa sọ ṣíwájú jijẹ ounjẹ?"

"Idahun- «BismiLlāhi» "
"Ti o ba gbagbe lati wi i ni ibẹrẹ rẹ, ki o sọ pe:"
"BismiLlāhi fii awwalihii wa aakhirihii» " "Abu Dāud ati Tirmidhiy ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 22: Ki ni waa sọ ti o ba jẹun tan?"

"Idahun- «AlhamduliLlāhi Lladhī at‘amanī hādha, wa razaqanīhi min gayri haolin minnī walā quwwata» " "Abū Dāud ati Ibnu Mājah ati ẹlomiran yatọ si awọn mejeeji ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 23: Ki ni adua ti alejo o ṣe fún ẹniti o ni ounjẹ?"

"Idahun- «Allāhummọ bārik lahum fīmā rọzaqTahum, wagfir lahum warhamhum» " Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 24: Ki ni ọmọniyan o sọ ti o ba sin?"

"Idahun- «AlhamduliLlāhi»."
"Ki ọmọ-ìyá rẹ tabi ọrẹ rẹ o sọ fun un pe: «Yarhamuka Llāhu»."
"Ti o ba ti waa sọ ọ fun un:
ki o yaa sọ pé: «Yahdīkumu Llāhu wa yuslihu bālakum» " "Al-Bukhāriy ni o gba a wa."

"Ibeere 25: Ki ni waa sọ ti o ba fẹ dìde nígbà ti o ba ṣetan ni ijokoo "Adua ipa aṣiṣe ijokoo rẹ (kaffāratul Majlis)"?"

"Idahun- «SubhānaKa Allāhummọ wa bi hamdiKa, ash’hadu an lā ilāha illā Anta, astagfiruKa wa atūbu ’illayKa» " "Abū Dāud ati Tirmidhiy ati ẹlomiran yatọ si awọn mejeeji ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 26: Ki ni adua gigun nkan ọ̀gùn?"

"Idahun- "BismiLlāh, wal hamdu liLlāh {Subhāna Lladhī sakhara lanā hādha wa mā kunnā lahu muqrinīn 13 wa innā ilā robbinā la munqalibūn 14} «AlhamduliLlāh, AlhamduliLlāh, AlhamduliLlāh, Allāhu akbar, Allāhu akbar, Allāhu akbar, subhānaKa Alllāhummọ innī zọlamtu nafsī fagfir lī; fa innahu lā yagfirid dhunūba illā Anta» " "Abū Dāud ati Tirimidhi ni wọn gba a wa."

Ibeere 27: "Darukọ adua irin-ajo?"

"Idahun- «Allāhu akbar, Allāhu akbar, Allāhu akbar {Subhāna Lladhī sakhara lanā hādha wa mā kunnā lahu muqrinīn 13 wa innā ilā robbinā la munqalibūn 14}, Allāhummọ innā nasaluKa fī safarinā hādhal birra wat taqwā, wa minal ‘amali mā tardọọ, Allāhummọ hawwin ‘alaynā safaranā hādha, watwi ‘annā bu‘dahu, Allāhummọ Antas Soohibu fis safari wal Khalīfatu fīl ahli, Allāhummọ innī a‘ūdhu biKa min wa‘thāis safari, wa ka’ābatil mansọri, wa sū’il munqọlabi fil māli wal ahli» "
"Ti o ba si ṣẹri pada yio sọ ọ, yio si tun fi kun un pe:'
"«'Āyibūna, tā’ibūna, ‘ābidūna, li Rabbinā hāmidūn» " Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 28: Ki ni adua ti arìnrìn-àjò o ṣe fun ẹniti o wa nile?"

"Idahun- «Astaodi‘ukumu Llāha Lladhī lā tadī‘u wadā’i‘uHu» " "Ahmad ati Ibnu Mājah ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 29: Ki ni adua ti ẹni tí o wa nile o ṣe fun arinrin-ajo?"

"Idahun- «Astaodi‘ul Lāha dīnaka, wa amānataka, wa khawātiima ‘amalika» " "Ahmad ati Tirmidhiy ni wọ́n gba a wa."

"Ibeere 30: Ki ni adua wiwọ inu ọja?"

"Idahun- «Lā ilāha illā Llāhu wahdaHu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul amdu, yuhyī wa yumītu, wa Huwa Ayyun lā yamūtu, bi yadiHil khayru, wa Huwa ‘alā kulli shay’in qadīr» " "Tirmidhiy ati Ibnu Mājah ni wọn gba a wa."

"Ibeere 31: Darukọ adua ti a maa n ṣe nigba ibinu?"

"Idahun- «’A‘ūdhu biLlāhi minash Shaytānir rajīm» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ibeere 32: Ki ni waa sọ fun ẹni tí o ba ṣe daadaa si ọ?"

"Idahun- «JazākaLlāhu khayran» " Tirmidhiy ni o gba a wa

"Ibeere 33: Ki ni adua ti a maa ṣe ti nkan ọ̀gùn ṣubú?"

"Idahun- «BismiLlāhi» " Abu Daud ni o gba a wa.

"Ibeere 34: Ki ni waa sọ ti nkan ti o dun mọ ọ ba ṣẹlẹ?"

"Idahun- «AlhamduliLlāhi Lladhī bi ni‘matiHi tatimmus sọọlihaat» " "Al-Hākim ati ẹni tí o yatọ si i ni wọn gba a wa."

"Ibeere 35: Ki ni waa sọ ti nkan ti o korira ba ṣẹlẹ?"

"Idahun- «AlhamduliLāhi ‘alā kulli hāl» " "Sọhīhul jāmi."

"Ibeere 36: Bawo ni sisalamọ ati dida salamọ pada?"

"Idahun- Musulumi o sọ pe: «As Salāmu alaykum wa rahmotuLloohi wa barakaatuHu» "
Ọmọ-iya rẹ maa da a lohun pe: «Wa alaykumus salāmu wa rahmotuLloohi wa barakaatuHu» " "O wa ni Tirmidhiy ati Abū Dāud ati awọn to yatọ si awọn mejeeji."

"Ibeere 37: Ki ni adua ti a maa sọ ni asiko rirọ ojo?"

"Idahun- «Allāhummọ soyyiban nāfi‘an» " "Al-Bukhāriy."

"Ibeere 38: Ki ni adua ti a maa n ṣe lẹyin rirọ ojo?"

"Idahun- «Mutirnā bi fadliLlāhi wa rahmatiHl» " Al-Bukhari ati Muslim.

"Ibeere 39: Sọ adua ti atẹgun ba n fẹ́?"

"Idahun- «Allāhummọ innī as'aluka khayrahā wa ’a‘ūdhu biKa min sharrihā» " "Abū Dāud ati Ibnu Mājah."

"Ibeere 40: Darukọ adua ṣiṣe nibi gbigbọ didun ara?"

"Idahun- «Subhāna Lladhī yusabbihur ra‘du bi hamdihii wal malāikatu min khīfatiHi» " Muwattahu Maalik

"Ibeere 41: Ki ni adua ti waa ṣe ti o ba ri ẹni tí adanwo kọlu?"

"Idahun- «AlhamduliLlāhi Lladhī ‘āfānī mimmā ibtalāka bihi, wa faddalanī ‘alā kathīrin mimman khalaqọ tafdīlah» " Tirmidhiy ni o gba a wa

"Ibeere 42: Adua ẹni tí ba n paya lati ma fi ojukoju ko adanwo ba nkankan?"

"Idahun- O wa ninu hadīth pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkan ti o wu u lọdọ ọmọ-ìyá rẹ tabi lọdọ ara rẹ, tabi nibi dukia rẹ, [ki o yaa ṣe adua alubarika fun un] tori pé dajudaju ojukoju ododo ni» " "Ahmad ati Ibnu Mājah ati ẹlomiran yatọ si awọn mejeeji ni wọn gba a wa."

"Ibeere 43: Bawo ni waa ṣe ṣe assalātu fun Anabi (ki ikẹ ati ọla maa ba a)?"

"Idahun- «Allāhummọ sọlli ‘alā Muhammadin wa ‘alā ’āli Muhammadin, kamā sọllayta ‘alā Ibrāhīma, wa ‘alā ’āli Ibrāhīma, innaKa Hamīdun Majīd, Allāhummọ bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā ’āli Muhammadin, kamā bārakTa ‘alā Ibrāhīma, wa ‘alā ’āli Ibrāhīma, innaKa Hamīdun Majīd» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.

"Ipin awọn nkan oríṣiríṣi"21

"Ibeere 1: Ki ni awọn idajọ ila-nnkan-bọni-lọrun maraarun?"

"Idahun-"
"1- Nkan ti o jẹ dandan."
"2- Nkan ti a fẹ."
"3- Nkan ti wọn ṣe ni eewọ."
"4- Nkan ti wọn korira."
"5- Nkan ti wọn ṣe ni ẹ̀tọ́."

"Ibeere 2: Ṣe alaye awọn idajọ maraarun yii?"

"Idahun-"
"1- Al-Wājib: Gẹgẹ bíi awọn Irun ọranyan maraarun, ati Aawẹ Ramadan ati ṣiṣe daadaa si obi mejeeji."
"- Al-Wājib, wọn maa san ẹni ti o ba ṣe e ni ẹsan, wọn si maa fi iya jẹ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ."
"2- Al-Mustahabbu: Gẹgẹ bíi àwọn sunnah awọn Irun ọranyan, ati qiyāmul layli ati fifun awọn eeyan ni ounjẹ, ati sisalamọ. Wọn si tun maa n pe e ni As-Sunnah ati Al-Madūb."
"- Al-Mustahabbu, wọn maa san ẹni ti o ba ṣe e ni ẹsan, wọn o si nii fi iya jẹ ẹni tí o ba gbe e ju silẹ."
"Akiyesi pataki:
"
"O tọ fun musulumi ti o ba gbọ wipe alamọri yii sunnah tabi mustahabbu ni ki o tara sasa lọ ṣe e, ki o si tun maa kọṣe Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a)."
"3- Al-Muharram: Gẹgẹ bíi mimu ọtí ati ṣiṣẹ obi mejeeji, ati jija okun ẹbi."
"- Al-Muharram, wọn maa san ẹni ti o ba gbe e ju silẹ ni ẹsan, wọn o si tun fi iya jẹ ẹni ti o ba ṣe e."
"4- Al-Makrūhu: Gẹgẹ bíi gbigba ati fifun pẹlu ọwọ osi, ati kika aṣọ ni ori Irun."
"- Al-Makrūhu, wọn maa san ẹni ti o ba gbe e ju silẹ ni ẹsan bẹẹ si ni wọn o nii fi iya jẹ ẹni ti o ba ṣe e."
"5- Al-Mubāhu: Gẹgẹ bíi jijẹ eso ajara (apple) ati mimu tíì, wọn si tun maa n pe e ni: Al-Jā’iz ati Al-Halāl."
"- Al-Mubāhu, wọn o nii san ẹni ti o ba gbe e ju silẹ ni ẹsan, bẹẹ si ni wọn o nii fi iya jẹ ẹni ti o ba ṣe e."

"Ibeere 3: Ki ni idajọ kata-kara ati ajọṣepọ?"

"Idahun- Ìpìlẹ̀ nibi gbogbo owo ati ajọṣepọ ni pe ẹtọ ni, ayaafi awọn iran kan ninu awọn nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ni eewọ."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀}" "[Sūratul Baqorah: 275]."

"Ibeere 4- Darukọ díẹ̀ nínú awọn ajọṣepọ ati awọn kata-kara ti o jẹ eewọ?"

"Idahun-"
"1- Irẹjẹ, ninu rẹ si ni: Fifi aleebu ọja pamọ."
"Lati ọdọ Abū Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi okiti ounjẹ kan, o wa ti ọwọ rẹ bọ inu rẹ, ni awọn ọmọnika rẹ ba kan nkan tutu kan, ni o ba sọ pe: «Ki ni eléyìí, irẹ oni ounjẹ?» O sọ pe: Ojo ni o pa a irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun. O sọ pe:" «O o ṣe fi i si oke ounjẹ ki awọn eeyan le ba ri i? Ẹni ti o ba ṣe irẹjẹ kii ṣe ara mi» " Muslim ni o gba a wa.
"2- Riba (Ele): Ninu ẹ ni ki n ya ẹgbẹrun kan ni ọwọ ẹnikan lori pe maa da ẹgbẹrun meji pada fun un."
"Alekun yẹn ni ele ti o jẹ eewọ."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀}" "[Sūratul Baqorah: 275]."
"3- Ẹtanjẹ ati Iruju (Aimọ): Gẹgẹ bíi ki n ta wara ti n bẹ ninu ọyan ẹran fun ọ, tabi ẹja ti n bẹ ninu omi ti mi o si tii dẹdẹ rẹ."
"O ti wa ninu hadīth pe:
(Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi òwò ẹtanjẹ)" Muslim ni o gba a wa.

"Ibeere 5: Darukọ diẹ ninu awọn idẹra Ọlọhun lori rẹ?"

"Idahun-1- Idẹra Isilaamu, ati pe o o si ninu awọn keferi."
"2- Idẹra sunnah, ati pe o o si ninu awọn oni adadaalẹ."
"3- Idẹra alaafia ati igbadun, nibi gbigbọ ati riri ati ririn ati èyí tí o yatọ si i."
"4- Idẹra jijẹ ati mimu ati wiwọ."
"Ati pe awọn idẹra Ọlọhun lori wa pọ ko ṣeé ka."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
"{Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́ 18}" "[Sūratun Nahl: 18]."

"Ibeere 6: Ki ni nkan ti o jẹ dandan nibi awọn idẹra? Ati pe bawo ni waa ṣe dupẹ rẹ?"

"Idahun- Nkan ti o jẹ dandan ni: Didupẹ rẹ, iyẹn ni pẹlu yiyin Ọlọhun ati didu ọpẹ fun Un pẹlu ahọn ati pe Oun nikan ṣoṣo ni o ni ọla, ati lílo idẹra yii sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ninu, ti kii ṣe sibi ṣiṣẹ Ẹ."

"Ibeere 7: Ki ni awọn ọdun awọn Musulumi?"

"Idahun- Ọdun itunu Aawẹ ati ọdun ileya."
"- Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu hadīth Anas, o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa si Medinah, wọn si ni ọjọ meji ti wọn fi maa n ṣere, o wa sọ pe: «Ki ni ọjọ mejeeji yii», wọn sọ pe: A maa n ṣere ninu ẹ ni igba aimọkan, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: "«Dajudaju Ọlọhun ti fi eyi ti o loore ju mejeeji lọ jirọ wọn fun yin: Ọjọ́ adhā (iléyá), ati ọjọ itunu Aawẹ» " "Abū Dāud ni o gba a wa."
"Eyi ti o ba si yatọ si mejeeji ninu awọn ọdun, ninu adadaalẹ ni."

"Ibeere kẹjọ: Èwo ni o daa julọ ninu awọn oṣu? "

"Idahun- Oṣu Ramadan. "

"Ibeere kẹsan-an: Èwo ni o daa julọ ninu awọn ọjọ? "

"Idahun- Ọjọ́ Jimọh. "

"Ibeere kẹwaa: Ọjọ́ wo ni o ni ọla ju nínú ọdun?

"Idahun- Ọjọ́ arafah. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkanla: Òru wo ni o ni ọla ju nínú ọdún?

"Idahun- Oru Laylatul Kọdri . "

"Ibeere ẹlẹẹkejila: Ki ni nnkan to jẹ dandan lati ṣe nigba ti o ba ri obinrin kan to jẹ ajoji? "

"Idahun- Nǹkan to jẹ dandan ni rirẹ oju nilẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: " "{Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀} "[Surah An-Nûr: 30]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Àwọn wo ni awọn ọta eniyan? "

"Ẹmi ti o maa n pani laṣẹ aburu: Ìyẹn ni pe ki eniyan maa tẹle nnkan ti ẹmi rẹ ba n sọ fun un ki o ṣe ati ifẹ-inu rẹ nibi ṣíṣẹ Ọlọhun- ti ibukun n bẹ fun Un ti ọla Rẹ ga-, Ọlọhun Ọba sọ pe: " "{dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run}. " [Suuratu Yusuf: 53]. "Eṣu: Oun ni ọta ọmọ Anabi Adam, ati pe ero rẹ ni pe ki o sọ eniyan nu ki o si ko royiroyi ba a nibi aburu ki o si mu u wọ ina. Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: " "{Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín}. " "[Surah Al-Baqarah: 168] "3- Awọn ọrẹ buruku: Àwọn to jẹ pe wọn maa n ṣe ni loju kokoro si aburu, ti wọn si maa n ṣẹri eeyan kuro nibi ohun rere. Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: " "{Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)} " [Suuratu Az-Zukhruf: 67].

Ibeere ẹlẹẹkẹrinla: ki ni o n jẹ ironupiwada? "

Idahun- Ìrònúpìwàdà: Oun ni ṣiṣẹri pada kuro nibi ṣiṣẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lọ si ibi itẹle E. Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: " "{Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà}. " "[Surah Al-taha : 82]"

"Ibeere ẹlẹẹkarundinlogun: Ki ni awọn majẹmu ironupiwada to ni alaafia? "

"Idahun- 1- Jijawọ nibi ẹṣẹ. "
2- Ṣiṣe abamọ lori nnkan to ti kọja.
"Ṣíṣe ipinnu lati ma pada si ibẹ mọ. "
"4- Dida awọn ẹtọ ati awọn nnkan ti wọn gba pẹ̀lú àbòsí pada fun awọn to ni i. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:
."{Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni) 135}. " "[Surah Âl-`Imrân: 135]"

"Ibeere ẹlẹẹkẹrindinlogun: Ki ni itumọ ṣíṣe asalaatu fun Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba-? "

"Idahun- Ìtumọ̀ ẹ ni pe ki o tọrọ lọdọ Ọlọhun lati ṣe ẹyin fun Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba- ni ọdọ àwọn mọlaika. "

"Ibeere ẹlẹẹkẹtadinlogun: Ki ni itumọ "Subhaanallah"? "

" Idahun- Ìṣe afọmọ ni fifọ Ọ mọ- mimọ ni fun Un ti Ọla Rẹ ga- kuro nibi gbogbo adinku ati aleebu ati aburu. "

"Ibeere ẹlẹẹkejidinlogun: Ki ni itumọ "Alhamdulillah"? "

"Idahun- Oun ni ṣiṣe ẹyin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati riroyin Rẹ pẹlu awọn iroyin pipe. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkandinlogun: Ki ni itumọ "Allahu Akbar"? "

"Idahun- Ìtumọ̀ rẹ ni pé Oun-mimọ ni fun Un- tobi ju gbogbo nnkan lọ, O si gbọnngbọn, O tobi, O lagbara ju gbogbo nnkan lọ. "

"Ibeere ogun: Ki ni itumọ Laa awla wa laa quwwata illaa billah? "

"Idahun- Ìtumọ̀ ẹ ni: Ẹrú ko le kúrò ninu iṣesi kan bọ sinu iṣesi mìíràn, ko si si agbara kankan fun un lori ìyẹn afi pẹlu Ọlọhun. "

"Ibeere ẹlẹẹkọkanlelogun: Ki ni itumọ Astagfirullah? "

"Idahun- Ìtumọ̀ rẹ ni: Ki ẹru beere lọwọ Ọba rẹ lati pa awọn ẹṣẹ rẹ rẹ ati lati bo awọn aleebu rẹ. "